Ẹsẹ kò gbèrò n'ilu Asaba lọ́jọ́ Mọnde ana nígbà tí àṣírí gendekunrin kan, Benson John tí wọn lo ń ṣe bíi wéré káàkiri ìlú náà, tó sì gbajumọ dáadáa wí pé kò sí nnkan tó ṣe é.
Ọdún mẹ́ta sẹ́yìn là gbọ pé Benson kúrò nile tó ń gbé n'ilu Port-Harcourt, ìpínlẹ̀ Rivers, to sì salọ sì ìlú Asaba, ìyẹn nipinlẹ Delta, níbi tó ti ń ṣe bíi alaaganna.
Látìgbà tí Benson tí kúrò nílé là gbọ pé àwọn mọlẹbi rẹ tí ń wá a, kò dá, tí wọn tún ti fọrọ náà tó àwọn ọlọpaa létí láti bá wọn wá a. Gbogbo akitiyan là gbọ pé ó já sí pàbó, tí wọn kò sì rí Benson.
Ọkàn lára àwọn mọlẹbi Benson là gbọ pé ó kofiri ẹ, tó sì bẹ̀rẹ̀ sii tọpinpin ẹ, kò tó o di pé àṣírí ẹ tú níbi tó ti ń paarọ aṣọ nínú ilé akọ̀ku kan. Nibẹ lo sì ti pariwo lè e lórí wí pé afi káwọn jọ de ilu tó fi silẹ.
Nígbà táwọn èèyàn fẹ ẹ bẹ̀rẹ̀ si í lu lo mú kó tú àṣírí ara rẹ síta wí pé oogun lòun lọọ ṣe lọ́dún mẹta sẹ́yìn, tí babaláwo sì sọ pé afi koun ṣe bíi were fún ọdún márùn-ún gbáko kí owó tó o de.
Benson ni ọdún mẹta péré lòun ṣí lo nínú ọdún márùn-ún náà, àti pé kí àṣírí má bá a tú lo jẹ́ koun rìn jìnnà síbi wọn tí dá òun mọ, àti pé òun kò mọ pe àṣírí máa tètè tú kí ọdún márùn-ún tó o pé.
No comments:
Post a Comment