Títí di àsìkò tí ẹ ń ka ìròyìn yìí l'ọrọ iyaale ilé kan tí wọn lo ó gùn ọkọ rẹ pá n'ijọba ibilẹ Itas-Gadau, ipinlẹ Bauchi ṣi ń jẹ fáwọn èèyàn.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oríṣiríṣi awuyewuye lo tí tá sì AWIKONKO létí nípa ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lọ́jọ́ Fraide ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí.
Lára ohun tá a gbọ ni pé oúnjẹ lo dá wàhálà àwọn t'ọkọ-tiyawo náà silẹ kò tó o di pé nnkan yiwọ mọ wọn lọ́wọ́.
A tún gbọ́ ọ̀rọ̀ ibalopọ lo dá wàhálà silẹ laarin wọn, tó fi di pé ìyàwó náà gùn ọkọ rẹ pá.
Àwọn ará àdúgbò là gbọ pé wọn ranṣẹ sáwọn ọlọ́pàá, tí wọn padà gbé òkú baálé ilé náà lọ sí mọṣuari, tí wọn sì tún gbé obìnrin náà lọ sí teṣan wọn láti f'ọrọ wá a lẹ́nu wo.
No comments:
Post a Comment