Ó TÁN! SANWÓ-OLÚ TU ÀṢÍRÍ BÍ ÀRÙN KORONAFAIRỌỌSI ṢE PỌ NÍ NÀÌJÍRÍÀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, April 30, 2020

Ó TÁN! SANWÓ-OLÚ TU ÀṢÍRÍ BÍ ÀRÙN KORONAFAIRỌỌSI ṢE PỌ NÍ NÀÌJÍRÍÀ


Gómìnà ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu tí jẹ kò di mimọ pé aitete tí àwọn ẹnu ibodè tó wọ orílẹ̀-èdè yìí pá lo ṣàkóbá fún itankalẹ àrùn aṣẹkupani Covid-19 ni Nàìjíríà. 
Ibi ifọrọwerọ kan tó ṣe pẹ̀lú ileeṣẹ CNN lọ́jọ́ Wẹside àná lo tí tú àṣírí náà síta. 
Sanwo-Olu ni kani ìjọba àpapọ̀ tètè tí àwọn ẹnu ibodè bíi papakọ ofurufu, àtàwọn ẹnubodè orí ilẹ̀, ó ṣeé ṣe kí àrùn náà tí kasẹ nílẹ̀ pátápátá. 
Ó ní èyí tó tún jẹ́ kí itankalẹ náà burẹkẹ sì í ní báwọn tó wọ Nàìjíríà láti òkè òkun ṣe kọ̀ láti fi ara wọn pamọ fún àyẹ̀wò. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI