O MA ṢE O! ỌLỌPAA YINBỌN PA GENDEKUNRIN LẸ́NU IṢẸ́ OOJỌ RẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, April 7, 2020

O MA ṢE O! ỌLỌPAA YINBỌN PA GENDEKUNRIN LẸ́NU IṢẸ́ OOJỌ RẸ


Ọga ọlọpaa nipinlẹ Abia, Ene Okon tí sọ pé ìwádìí tí bẹ̀rẹ̀ lórí ọlọpaa tó yinbọn pá gendekunrin kan tí wọn pé orúkọ rẹ ni Chibuisi lopopona New Umuahia, ìjọba ìbílẹ̀ Obingwa. 

Ọlọpaa náà tí wọn pé orúkọ rẹ ni Stanley Azu ni wọn lo o lè awakọ kan tó tàpá sì òfin konilegbele nipinlẹ náà, tí wọn sì ni ṣe ló lè e de ibi tí Chibuisi wá. 

Bo ṣe debẹ ni wọn lo ó ti dá ìbọn bolẹ, tí ìbọn náà sì bá Chibuisi, lójú ẹsẹ lo tí ku, táwọn èèyàn sì gbé e lọ sí ọsibitu àwọn olukọni, ìyẹn Abia State Teaching Hospital fún itọju, nibẹ sì ni wọn ti sọ pé òkú lẹni tí wọn gbé wa. 


Ilé-epo Greenmac Energy Ltd to jẹ ti ọkan lára ọkọ ẹ̀gbọ́n rẹ ni Chibuisi tí ń ṣíṣẹ, nibẹ sì ni ọlọpaa yìí pá a dànù sì. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI