Ko sẹni to rí bàbà arúgbó kan tí wọn pé orúkọ rẹ ni Akinpẹlu Bọladalẹ, ẹni ọdún mẹrindinlọgọta {56years} lórí bẹẹdi l'ọsibitu LUTH n'ilu Eko níbi tó ti ń jẹ ìrora, àánú abiyamọ yóò ṣe é.
Ko si nnkan méjì tó dá Akinpẹlu Bọladalẹ dubulẹ l'ọsibitu bí kò ṣe ti àìsàn jẹjẹrẹ inú ẹ̀jẹ̀ tí wọn lo ń dá a láàmú láti bí oṣù mélòó kan sẹ́yìn.
Ọdún tó kọjá là gbọ́ pé Baba yìí dubulẹ àìsàn, tí wọn sì gbé e káàkiri oríṣiríṣi ọsibitu, níbi tí wọn padà tí ṣàyẹ̀wò fún un, tí wọn sì rí í pé àìsàn jẹjẹrẹ inú ẹ̀jẹ̀ lo ń yọ ọ lẹ́nu.
Yàtọ̀ sí èyí, wọn ní oríṣiríṣi àyẹ̀wò ni wọn ti ṣe fún bàbá Akinpẹlu Bọladalẹ, ọmọ bibi abúlé Abalabi nijọba ìbílẹ̀ Ewekoro, Ìpínlẹ̀ Ogun, tí wọn sì fìdí ẹ múlẹ̀ pé iṣẹ abẹ nikan ni wọ́n lè ṣe fún un láti doola ẹ̀mí rẹ.
Iṣẹ gbẹ́nàgbẹ́nà, ìyẹn Carpenter là gbọ pé Bọladalẹ ń ṣe lágbègbè Mushin, ipinlẹ Eko láti bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn.
A gbọ pé ẹlẹyinju àánú ni Bọladalẹ, tó sì tí rán ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn lọ́wọ́, kò dá, tí wọn ní kó sẹni tí kò lè ṣàánú fún nígbà tí ara rẹ yà gidi, táwọn èèyàn sì mọ-ọn dáadáa.
Ori àìsàn yìí là gbọ pé Baba náà tá pupọ nínú dúkìá rẹ sì í, tàwọn mọlẹbi rẹ sì ti na ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó lórí àìsàn yìí bákan náà.
Ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí ni wọn làwọn dọkita sọ pé miliọnu méjì ataabọ {N2.5m} náírà ni owo ti wọn nílò láti fi ṣiṣẹ abẹ náà ni kíákíá, ìyẹn kò tó o pẹ ju.
Yatọ si eyii, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá-mẹ́wàá {N10,000} náírà là gbọ pé wọn ń ná lórí oogun láàrin ọjọ mẹ́ta-mẹ́ta fún itọju.
Nígbà tí agbára kò fẹ́ ẹ gbé mọ lo jẹ́ kí wọn wá sí ileeṣẹ AWIKONKO láti béèrè fún iranlọwọ àwọn ẹlẹyinju àánú ọmọ Nàìjíríà káàkiri àgbáyé.
Ẹyin ẹlẹyinju àánú, ẹ̀bẹ̀ là ń bẹ yín láti rán Ọgbẹni Akinpẹlu Bọladalẹ lọ́wọ́. Kò sí ìyè owó tó kéré jù láti fi rán bàbà yìí lọ́wọ́ kò má bá a kú ikú òjìji.
Gbogbo àwọn ìwé ọsibitu tí wọn gbé Bọladalẹ lọ lo wá larọwọto ileeṣẹ wá gẹ́gẹ́ bí aridaju, àti pàápàá fáwọn tó bá fẹ́ ẹ rí í fún àánú.
Fún ẹyin ti ẹ ba fẹ́ ẹ rán bàbà yìí lọ́wọ́, èyí ni àpò owó ilé ifowopamọ tí ẹ lè fowo ranṣẹ sì, kò dá, ẹ tún lè pé Baba yìí lórí fóònù láti béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ẹ síwájú sii.
ORUKO: AKINPẸLU BỌLADALẸ A
AKANTI NỌ́MBÀ: 0208061013
BANKI: FCMB
Ẹ̀RỌ IBANISỌRỌ: 08032384816
No comments:
Post a Comment