B
í ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí, inú àìsàn ńlá ni ogbontarigi agba-ọjẹ oṣere tíátà nnì, Alaaji Kaṣimawo Yẹkini Oloyede wá bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí, kò dá, ilé tó ń gbé kò yẹ fún ẹranko láti gbé, depodepo èèyàn ẹlẹran ara.
Alaaji Yẹkini t'ọpọ àwọn èèyàn mọ sì Baba Lẹgba là gbọ pé àìsàn ẹsẹ lo dá a dubulẹ láti bí ọdún kan sẹ́yìn.
Kí í ṣe akọkọ re e táwọn èèyàn, pàápàá àwọn olólùfẹ́ àwọn oṣere tíátà yóò máa sọ pé àwọn èèyàn náà kò fẹ́ràn ara wọn, torí pé wọn kì í rán ara wọn lọ́wọ́ lásìkò ìṣòro.
O ṣeni láàánú pé nnkan ti dàrú fún Baba Lẹgba gidi lásìkò yìí, nítorí tá a gbọ pé kò rowo jẹun bí í tí tẹ́lẹ̀ mọ.
Ọ̀pọ̀ ìgbà là gbọ pé Baba náà ń tọrọ owó káàkiri láti fi jẹun, ṣùgbọ́n nígbà tí àìsàn yìí dáa dubulẹ, kò rí owó jẹun mọ. A tiẹ̀ gbọ pé ọpọ ìgbà l'ọkunrin náà tí pé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ nìdí iṣẹ náà fún iranlọwọ owó, ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé owó tí wọn ń fún un kí í tó nnkan.
Laipẹ yìí ni fọ́nrán kan tẹ AWIKONKO lọ́wọ́, èyí tí gbajumọ sọrọsọrọ kan ṣe fún un nílé rẹ tó ń gbé lágbègbè Itoku, Abẹ́òkúta, nibẹ lo sì ti sọ pé òun kò lè rìn mọ.
Látìgbà táwọn oṣere tíátà kò ti pé Baba yìí siṣẹ mọ ni wọ́n lo tí ń ṣagbe. Títí di asiko tá a fi parí ìròyìn, àwọn oṣere tíátà kò yọjú sì Bàbà Lẹgba láti wo àlàáfíà ẹ, depodepo wí pé wọn yóò fún un lowo.
Fawọn to bá fẹ́ ẹ rán Baba Lẹgba lọ́wọ́
Bank: Diamond/Access
Account Number: 0079858680
Name: Kashimawo Yekini Oloyede
Phone: 07080504716
Fawọn to bá fẹ́ ẹ rán Baba Lẹgba lọ́wọ́
Bank: Diamond/Access
Account Number: 0079858680
Name: Kashimawo Yekini Oloyede
Phone: 07080504716
Fọ́nrán náà re e:
No comments:
Post a Comment