Epe rabande-rabande l'awọn eeyan, paapaa awọn to sunmọ akẹkọọ fasiti ọgbin n'ilu Abẹokuta, Ṣeyi Akinade n gbe awọn ọlọpaa SARS ṣẹ lori bi wọn ṣe ṣokunfa iku ẹ.
Ṣeyi la gbọ pe o ṣalaye sori ikanni ayelujara ti Twitter lai pẹ yii pe awọn ọlọpaa lo ko oun sinu gbese ayeraye titi d'asiko toun fi gbe majele jẹ.
AWIKONKO gbọ pe awọn ọlọpaa lati Ibara ni wọn lọ gbe Ṣeyi atawọn ọrẹ rẹ nile lọsu keji ọdun yii, ti wọn si fẹsun jibiti kan wọn. Gbogbo akitiyan Ṣeyi lati jẹ kawọn ọlọpaa mọ pe oun ki i lu jibiti, ati pe oun ki i jale lo ja si pabo lọjọ naa.
Laipẹ yii ni Ṣeyi gbe majele jẹ, to si jẹ pe nigba t'awọn eeyan yoo fi mọ, ẹpa ko boro mọ, paapaa nigba ti wọn maa gbe e de ọsibitu, o ti dagbere faye.
Agbenusọ f'awọn ọlọpaa, Abimbọla oyeyẹmi sọ pe oun ko ti i gbọ nnkankan nipa iṣẹlẹ naa, ṣugbọn toun yoo ṣe iwadii.
Ọpọ awọn to gbọ siṣẹlẹ naa ni wọn n bẹ ijọba lati ma jẹ ki iku Ṣeyi ti wọn lo o padanu owo ti ko din ni egberun lọna ogun dọla ($20,000) lọ lasan.
No comments:
Post a Comment