Afaimọ ni kí ọmọbìnrin kan tí wọn pé orúkọ rẹ ni Idowu Adekọya má padà fojú bá ilé ẹjọ́ lórí fọ́nrán tó gbé sórí ìkànnì ayélujára, níbi tó ti ń ṣepe ńlá-ńlá fún gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun; alaga ìjọba ibilẹ Ìjẹ̀bú-Òde àti igbakeji rẹ lórí oúnjẹ konilegbele tí wọn gbé fún un.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Idowu tí yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ padà wí pé àṣìṣe ni fọ́nrán náà tòun gbé jáde, àti pé irẹsi àti ẹwà tòun sọ pé majele ni, lójú ẹsẹ làwọn tí se e jẹ, kò dá tó ní mọin-mọin lòun fi ṣe.
Fọ́nrán tí Idowu gbé jáde yìí káàkiri orí ìkànnì ayélujára lọsẹ tó kọjá yìí, táwọn èèyàn sì ń sọ̀rọ̀ lórí ẹ.
Ni kété tí fọ́nrán náà tí tẹ àwọn aṣojú gomina Abiọdun lọ́wọ́ ni wọn ti gba ilé Idowu lọ láti lọ ṣe ìwádìí, ṣùgbọ́n tó sọ pé irọ́ lásán lòun pá nibẹ, tó sì bẹbẹ fún ìdáríjì.
Loju ẹsẹ làwọn ọlọpaa tí gbé Idowu lọ teṣan níbi tó ti lọ ọ sọ nnkan tó rí, tó fi gbé fọ́nrán náà síta láti bá orúkọ Gómìnà Abiọdun jẹ́ káàkiri àgbáyé, tí wọn sì padà gba beeli ẹ wí pé yóò ṣí padà wá.
AWIKONKO gbọ́ pé ẹnikan tí wọn pé orúkọ rẹ ni Toyin Alawiye tí kò fẹran alaga ìjọba ibilẹ Ìjẹ̀bú-Òde tí wọn yàn síbẹ̀ lo ṣagbatẹru fọ́nrán naa.
Òun náà lo sì pín fọ́nrán náà ká sórí ìkànnì ayélujára láti fi bá orúkọ alaga náà jẹ, tó sì jẹ pe pupọ àwọn tó ṣalabapade fọ́nrán yìí ni wọn ń gbé alaga náà ṣepe.
Lára awkn tó sunmọ ìjọba ipinlẹ Ogun tí sọ pé àwọn ń retí kí konilegbele yìí kasẹ nilẹ tán ni káwọn tó o mọ igbesẹ tó kú, àti pé ó ṣeé ṣe kí Idowu fojú bá ilé ẹjọ́ láti kọgbọn.
Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin tó jẹ́ akọwe ìròyìn fún gomina bù ẹnu atẹ lu ìwà tí Idowu hu náà, tó sì sọ pé ó kú díẹ̀ kaato.
No comments:
Post a Comment