NÍTORÍ ÌWÉ TÓ MỌ JÙ WỌN LỌ, SAMSON ÀTI EMMANUEL GBIMỌ LATI PA ỌRẸ WỌN DÀNÙ - IROYIN AWIKONKO

Sunday, April 12, 2020

demo-image

NÍTORÍ ÌWÉ TÓ MỌ JÙ WỌN LỌ, SAMSON ÀTI EMMANUEL GBIMỌ LATI PA ỌRẸ WỌN DÀNÙ

IMG_ORG_1586700879749

Bí kí í bá a ṣe orí tó ko ọmọdékùnrin kan, Timothy Oluwatobi Adeniyi yọ lọ́wọ́ àwọn ọrẹ rẹ tí wọn fẹ ẹ paa dànù ni, bóyá kí bá ti dero ọrùn bí a ṣe ń kọ ìròyìn yìí.

Titi di asiko tá a fi kọ ìròyìn yìí tán là gbọ pé Timothy ṣí wá lọsibitu, níbi tó ti ń gba ìtọ́jú torí pé wọn tí gun-un l'ọbẹ. 

Ohun tá a gbọ ni pé àwọn ọrẹ Timothy, Ademọla Emmanuel, ọmọdun mẹrindinlogun {16} àti Samson Badejọ tòun je ọmọdun méjìdínlógún {18} ni wọn fẹsun kan án wí pé ó mọ ìwé ju àwọn lọ. 

Wọn ní àwọn òbí Emmanuel àti Samson máa ń fi Timothy bù wọn wí pé ó yẹ kí wọn wò awọkọṣe ẹ, káwọn náà sì lè tẹra mọ ẹ̀kọ́ wọn dáadáa. 

IMG_ORG_1586701623876

Òpó ìgbà ni wọn ní Timothy tí gba àmì ẹyẹ fún iléèwé wọn, kò dá tí wọn loo gbajumọ dáadáa ládùúgbò wọn nípa ìwé tó mọ náà, tó sì tún ja fafa. 

Ṣe là gbọ pé Emmanuel àti Samson gbimọ papọ láti pá Timothy nítorí ìtìjú tó ń kó bá wọn, kò tó o pẹ ju, ìyẹn nígbà tí wón ń múra láti padà sẹnu ẹ̀kọ́ wọn. 

Àṣírí wọn lo tú síta nígbà tí wọn tán Timothy lọ sínú ahere kan nibi ti wọn fẹ ẹ pá a dànù sì, tí ọwọ palaba wọn sì segi. 

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun tí fìdí rẹ múlẹ̀ pé lóòótọ́ niṣẹlẹ, àti pé dandan ni káwọn méjèèjì fojú bá ilé ẹjọ́ pẹ̀lú ẹ̀sùn igbiyanju láti paayan lẹ́yìn tí ìwádìí bá túbọ̀ parí. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI

Contact Form

Name

Email *

Message *