NÍTORÍ FUNKẸ AKINDELE, ỌWỌ ỌLỌPAA TẸ GBADAMỌSI, OLUDIJE SÍPÒ GÓMÌNÀ L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, April 7, 2020

NÍTORÍ FUNKẸ AKINDELE, ỌWỌ ỌLỌPAA TẸ GBADAMỌSI, OLUDIJE SÍPÒ GÓMÌNÀ L'EKOO


Bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí, ọkàn lára àwọn tó yọjú síbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí tí Funkẹ Akindele-Bello ṣe fún ọkọ rẹ tọwọ ọlọpaa tún ti tẹ báyìí ni oludije sípò gómìnà Eko lọ́dún 2019, ìyẹn Babatunde Gbadamọsi tọpọ tún mọ sì BOG. 

Ana la gbọ pe ọwọ ọlọpaa tẹ ọkùnrin náà lẹ́yìn tí wọn kofiri rẹ nínú fọ́nrán ayẹyẹ náà tí wọn gbé sórí ìkànnì ayélujára.

Oludije sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Eko labẹ asia ẹgbẹ́ òṣèlú Action Democratic Party (ADP) ni Gbadamọsi nínú idibo tó kọjá, ìyẹn 2019.

Atimọle ọlọpaa là gbọ pé ọkùnrin náà wá láti àná, ìyẹn Mọnde, tá a sì gbọ wí pé wọn kò ní í fi silẹ lai jẹ pe o foju bá ilé ẹjọ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI