NITORI AYẸYẸ ỌJỌ IBI LASIKO GBELE Ẹ, ỌWỌ ỌLỌPAA TẸ FUNKẸ AKINDELE, NI NAIRA MARLEY, ẸNIỌLA BADMUS AT’AWỌN MI-IN BA NA PAPA BORA. - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, April 6, 2020

NITORI AYẸYẸ ỌJỌ IBI LASIKO GBELE Ẹ, ỌWỌ ỌLỌPAA TẸ FUNKẸ AKINDELE, NI NAIRA MARLEY, ẸNIỌLA BADMUS AT’AWỌN MI-IN BA NA PAPA BORA.

‘Aye mi, temi ba mi’ lọrọ ti wọn ni gbajumọ oṣere tiata nni, Funkẹ Akindele Bello mu sẹnu lọjọ Aiku, Sande ana n’igba tọwọ ọlọpaa tẹ ẹ lori bo ṣe lugbadi ofin konilegbele t’ijọba ṣe l’ọsẹ to kọja yii.

Fiimu l’ọpọ awọn to wa lagbegbe ti Funkẹ Akindele t’awọn eeyan tun n pe ni Jẹnifa n gbe, iyẹn Amen Esate to wa lopopona Ajah si Ibẹju-Lẹkki, Eko ro pe wọn n ya n’igba ti wọn n gburo mọto awọn ọlọpaa n’irọlẹ ana.

Kani Funkẹ mọ pe ibi ti ọrọ naa yoo ja si n’iyẹn, boya ko ba ti ṣe ayẹyẹ naa ni bonkẹlẹ, ki wọn si gbagbe ẹrọ ayelujara patapata, tori pe itiju nla gba a lo jẹ fun un n’igba t’ọrọ naa jade sita.

Ayẹyẹ ọjọ ibi ọkọ Funkẹ, iyẹn Abdulrasheed Bello t’awọn eeyan tun mọ si JJC Skills la gbọ pe Funkẹ pe awọn ọrẹ rẹ, paapaa awọn ti wọn jọ wa n’idi iṣẹ tiata lati b’oun fi imọriri han si i.

Ọsẹ to kọja n’ijọba kede konilegbe fun ọjọ mẹrinla gbako lati fi dẹkun itankalẹ aarun Coronavirus, ti wọn si gbe awọn ofin sita lori ẹni to ba tapa si ofin naa. Wọn ni ko gbọdọ si ipejọpọ eeyan to le ni ogun, depodepo wi pe wọn yoo ṣe ayẹyẹ kankan. Lara awọn ijiya to to wa fun ẹni to ba tapa si ofin naa ni ẹwọn oṣu mẹta gbako tabi owo itanran ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira (100,000).

AWIKONKO gbọ pe b’awọn eeyan ṣe ri fọnran ayẹyẹ naa lori ẹrọ ayelujara ti Instagram lo mu ki wọn pe akiyesi awọn ẹka ijọba si i wi pe ki wọn tete ṣe iwadii awọn eeyan naa, ti wọn si ri i pe Funkẹ Akindele lo wa n’idi ayẹyẹ naa.

Ohun ta a gbọ ni pe awọn to le ni ọgọrun kan (100+) l’awọn to wa nibi ayẹyẹ naa lana-an, ti wọn si n di mọ ara wọn. Loju ẹsẹ la gbọ pe ọga ọlọpaa ipinlẹ Eko ti paṣẹ wi pe ki wọn lọ ọ ko awọn eeyan naa.

Lara awọn to wa nibi ayẹyẹ naa ni Ẹniọla Badmus, Afeez Faṣọla, iyẹn Naira Marley at’awọn mi-in to lorukọ lagboole amuludun.

Wọn ni b’awọn to wa ninu ile ti Funkẹ ati ọkọ rẹ, JJC n gbe ṣe ri mọto awọn ọlọpaa ni wọn ti na papa bora, to fi mọ Naira Marley ati Ẹniọla Badmus.

Ohun to n ya awọn eeyan lẹnu ju nibẹ ni bo ṣe jẹ pe Funkẹ Akindele to jẹ aṣoju ileeṣẹ to n ri sọrọ ajakalẹ arun, NCDC, ẹni to tun n d’awọn eeyan lẹkọọ lori awọn nnkan to yẹ ki wọn ṣe lasiko konilegbele ati pe ki wọn ma ṣe ṣẹ si ofin naa lo tapa si ofin yii.

Bi ọwọ ṣe tẹ Funkẹ lo ti sare ṣe fọnran, to si gbe e sori ẹrọ ayelujara wi pe k’awọn ọmọ Naijiria foriji oun nitori pe oun mọ pe itiju nla lo jẹ f’oun, ati pe oun ko mọ pe bi yoo ti ri niyẹn.

Funkẹ Akindele sọ ninu fọnran naa wi pe ki i ṣe pe oun pe ero jọ, ati pe gbogbo awọn to wa nibi ayẹyẹ naa lo jẹ pe wọn ti wa lagbegbe naa ki eto konilegbele to o bẹrẹ rara, to si jẹ pe ile toun n gbe, iyẹn nibi t’awọn ti n ya fiimu Jẹnifa lo jẹ pe awọn to le ni ọgọrun kan lo n gbebẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Bala Elkana n’igba to n sọrọ sọ pe bi Ẹniọla ati Naira Marley ko ba tete yọju ki ilẹ ọjọ Aje, iyẹn Mọnde onii to o ṣu, o ṣee ṣe k’awọn fi fọto wọn sita gẹgẹ bi ọdanra ti wọn n wa.

Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, afaimọ ni ki Funkẹ Akindele ati ọkọ rẹ ma pada ṣewọn oṣu mẹta, tabi ki wọn san owo itanran ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan naira gẹgẹ bi owo itanran.

Awuyewuye to n lọ kaakiri ori ikanni ayelujara bayii, eyi ti AWIKONKO ko ti i le fidi rẹ mulẹ ni pe ileeṣẹ NCDC ti Funkẹ Akindele jẹ aṣoju wọn ti gba ipo aṣoju naa kuro lọwọ rẹ lori bo ṣe doju ti wọn, paapaa awọn ọmọ Naijiria, ti wọn si l’awọn ko le ba ẹni ti ko le tẹle ofin ṣiṣẹ papọ.

Wọn ni gbogbo ibi ti Funkẹ Akindele ti ṣe fọnran fun wọn ati awọn aworan rẹ ni wọn ti yọ danu, ti wọn si ti n wa ẹlomi-in ti wọn yoo gbe iṣẹ naa fun bayii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI