NÍTORÍ ÀWỌN TÓ Ń FI ORÚKỌ RẸ LU JÌBÌTÌ, OLUKỌYA, PASITỌ MFM PARIWO SÍTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, April 13, 2020

NÍTORÍ ÀWỌN TÓ Ń FI ORÚKỌ RẸ LU JÌBÌTÌ, OLUKỌYA, PASITỌ MFM PARIWO SÍTA


Alakoso àti oludasilẹ ṣọọṣi Orí-Òkè Ina àti Iṣẹ Ìyanu {Mountain of Fire and Miracles Ministries} Dọkita Daniel Kọlawọle Olukọya tí gba gbogbo àwọn èèyàn, pàápàá àwọn tó wà lórí ìkànnì ayélujára lamọran wí pé kí wọn ṣọ́ra fáwọn tó ń fi orúkọ òun lu jìbìtì.

Oni tí í ṣe ọjọ́ Ajé, ìyẹn ọjọ́ Àjíǹde ni Dọkita Olukọya sọ̀rọ̀ náà jáde wí pé òun kò dá àjọ aláàánú kankan silẹ, èyí tí yóò mú koun máa béèrè owó iranlọwọ lọ́wọ́ àwọn èèyàn.

Ṣáájú asiko yii là gbọ pé àwọn kan lórí ìkànnì ayélujára tí fesibuuku tí lọọ gbé fọto àti orúkọ alakoso ṣọọṣi MFM náà síta, tí wọn sì ń fi atẹjiṣẹ ranṣẹ sáwọn èèyàn. 

Nínú àwọn atẹjiṣẹ náà là gbọ pé wọn tí ń béèrè owó fún àkànṣe àdúrà àti iranlọwọ fáwọn aláìní. Pupọ àwọn tí wọn rí atẹjiṣẹ náà gbà là gbọ pé wọn tí fi owó ranṣẹ, bo tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí ìwà jìbìtì náà ye dáadáa kò kò sakolo wọn.

Olukọya ni níbi tòun de lónìí, òun ni í béèrè owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni láti gbàdúrà fún un, àti pé òun kò dá àjọ aláàánú kankan silẹ, fún ìdí èyí, ó ní báwọn èèyàn bá ti ń gba atẹjiṣẹ náà, ki wọn má ṣe dáhùn.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI