Ìjọba Ìpínlẹ̀ Eko ti sọ ìdí pàtàkì tí wọn ṣe fi gbajumọ olorin takasufee nnì, Azeez Faṣọla, gbajumọ olóṣèlú nnì, Babatunde Gbadamọsi àti ìyàwó ẹ, Fọlaṣade Gbadamọsi silẹ wí pé kí wọn máa lọ layọ àti àlàáfíà.
Ohun tá a gbọ ni pé àwọn èèyàn náà gbà láti kọ lẹ́tà ẹ̀bẹ̀ sijọba Ìpínlẹ̀ Eko lórí bí wọn ṣe tàpá sì òfin konilegbele tijọba pàṣẹ rẹ.
Nínú lẹ́tà ẹ̀bẹ̀ ti wọn yoo kọ ranṣẹ sijọba ni wọn yóò ti fi dá ìjọba lójú wí pé wọn yóò mú òfin igbele ọlọjọ mẹ́rìnlá náà lo, àti pé gbogbo àṣẹ tijọba àpapọ̀ pá ni wọn yóò tẹle.
No comments:
Post a Comment