KWARA BẸRẸ PINPIN OWO KONILEGBELE F'AWỌN ARAALU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, April 23, 2020

KWARA BẸRẸ PINPIN OWO KONILEGBELE F'AWỌN ARAALU

L'ọjọ Aje, Mọnde ana n'ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina Abdulrasaq bẹrẹ pinpin owo f'awọn araalu lasiko konilegbele to n lọ lọwọ yii.

Eto naa ti wọn pe ni 'Owo Arugbo' ni wọn bẹrẹ kaakiri ijọba ibilẹ Ọfa ati Oyun, to si jẹ pe pupọ awọn arugbo to wa nibẹ ni wọn ti jẹ anfaani yii.

Abẹ ajọ kan to jẹ tíjọba, eyi ti wọn pe ni Kwara State Social Investment Program (KWASSIP) ni wọn ti gbe eto naa kalẹ lati fi ran awọn araalu, paapaa awọn agbalagba lọwọ lasiko konilegbele fun idẹkun itankalẹ arun COVID-19.
AWIKONKO gbọ pe awọn t'ọjọ ori wọn bẹrẹ lati ọgọta ọdun {60years} ni wọn lẹtọọ si anfaani yii, t a asi tun gbọ pe wọn ti bẹrẹ si i gba orukọ awọn eeyan si;ẹ kaakiri ijọba ibilẹ Ilọrin West, East ati South.

Yatọ si eyi, wọn tun n lo anfaani naa lati ṣe ayẹwo fawọn eyan lati mọboya wọn ni arun koronafairọọsi lara, ki wọn le tete bẹrẹ itọju fun wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI