Ko si orin méjì táwọn èèyàn ń kọ lásìkò yìí bí kò ṣe orin tí ọkàn pàtàkì lára àwọn ogbontarigi olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ gbogboniṣe tí Moshood Abiọla tó wà n'ilu Abẹ́òkúta, Ọgbẹni Olufẹmi Ọrunṣọla gbé jáde laipẹ yìí fún tí aarun àṣekupani tí Koronafairọs to ń dá gbogbo àgbáyé láàmú lákòókò yìí.
Orin náà tó pé ní "CORONA GBẸRU Ẹ" lo kún fún ọgbọ́n àti idanilẹkọọ alailafiwe, kò dá to tún borí àwọn àwo orin táwọn olorin kan tí gbé jáde sẹyin.
Gbajugbaja ni Ọrunṣọla, ẹni tọpọ mọ sì 'Awe' nìdí iṣẹ orin kíkọ, pàápàá laarin awọn olùkọ́ lẹka ikẹkọọ eto ikansira-ẹni àti ibara-ẹni-sọrọ, ìyẹn Mass Communications lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Nínú orin náà lo tí ṣàpèjúwe aarun Koronafairọs tí wọn tún ń pè ní COVID-19 gẹ́gẹ́ bí i Personae Non Grata.
Bí orin náà ṣe jáde síta là gbọ pé àwọn ileeṣẹ rédíò àti tẹlifiṣan tí bẹ̀rẹ̀ si í béèrè fún un láti máa lo ó fáwọn èèyàn láti kẹ́kọ̀ọ́.
Nnkan tó tún jẹ́ kí orin náà gbayì kọjá sísọ ni bi fọ́nrán àwo orin náà to jáde nirọlẹ Tuside àná ṣe kún fún ọpọlọpọ ere àti awada.
No comments:
Post a Comment