KONILEGBELE: ÀWỌN ỌLỌPAA YINBỌN PA ÈÈYÀN MẸ́FÀ LÁÀRIN ỌJÀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, April 7, 2020

KONILEGBELE: ÀWỌN ỌLỌPAA YINBỌN PA ÈÈYÀN MẸ́FÀ LÁÀRIN ỌJÀ


Ṣe lọrọ náà dabi fíìmù lọ́jọ́ Aje, Mọnde àná nígbà táwọn ọlọpaa yawọ gbajumọ ọjà Trikania tó wà ni Sabogeri Nasarawa nijọba ìbílẹ̀ Chikun, ìpínlẹ̀ Kaduna, tí wọn sì pá èèyàn ti ko dín ni márùn-ún.

Àwọn ọdọ àtàwọn ọlọpaa ni wọn kọjú ìjà sí ara wọn lásìkò tí konilegbele ń lọ lọ́wọ́ káàkiri Nàìjíríà, pàápàá lagbaaye.

Ohun tá a gbọ ni pé ṣe làwọn èèyàn kò ara wọn jọ, tí wọn sì dá ọjà kékeré kan silẹ lágbègbè ọjà Trikania yìí. 

Eyi ni wọn làwọn eleto ààbò araalu kan tí wọn pé ní Civilian Joint Task Force rí, tí wọn fi dìde láti lọọ lè àwọn èèyàn náà kúrò, ṣùgbọ́n tí wọn làwọn ọdọ tó wà nibẹ kò gbà láàyè láti lè wọn dànù. 

Nígbà tí wọn ní agbara àwọn eleto ààbò naa ko ká wọn, lo mú kí wọn ranṣẹ sáwọn ọlọpaa Kakuri láti wá a rán wọn lọ́wọ́.

Wọn ní lójú ẹsẹ táwọn ọlọpaa tí de bẹ ní wọn tí dá ìbọn bolẹ láti lè àwọn èèyàn danu, táwọn márùn-ún sí kú lójú ẹsẹ. 

Àwọn tí kò lonka là gbọ́ pé fara gba ọta ìbọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò kú, ṣùgbọ́n síbẹ̀, wọn farapa yanna-yanna gẹ́gẹ́ bá a ṣe gbọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI