KO SI IBÙDÓ AYẸWO COVID-19 NI UCH IBADAN - ỌGA ÀGBÀ PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, April 25, 2020

KO SI IBÙDÓ AYẸWO COVID-19 NI UCH IBADAN - ỌGA ÀGBÀ PARIWO SITA


Ọ̀ga àgbà fún ilé iwosan UCH, Ọjọgbọn Jesse Abiodun Otegbayo lọ ṣísọ lójú ọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó ń gbalejo kọmisana feto ìlera nipinlẹ Ọ̀yọ́, Dókítà Bashir Bello nílé ìwòsàn náà.

Atẹjade kan tí ilé ìwòsàn UCH wá fi síta lẹ́yìn abẹwo naa ni lóòótọ́ nile ìwòsàn náà ń tọju afurasi alárùn Covid-19 kan lọ́wọ́ àmọ́ wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ayẹwo rẹ ransẹ sì ikọ ìjọba tó ń ṣe ayẹwo àrùn Coronavirus ni.

Atẹjade náà fikùn pé, ilé ìwòsàn UCH sì ń dúró de èsì ayẹwo náà láti ibùdó ayẹwo níta, táwọn yóò si maa fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó aráyé létí bo ba ṣe ń lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI