KAYEEFI! ÒKÚ BAÁLÈ ILÉ TI WỌN RÍ LETI ODÒ DI IBẸRUBOJO F'ÁWỌN ARÁÀLÚ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, April 7, 2020

KAYEEFI! ÒKÚ BAÁLÈ ILÉ TI WỌN RÍ LETI ODÒ DI IBẸRUBOJO F'ÁWỌN ARÁÀLÚ


AWIKONKO gbọ pé ìwádìí tí bẹ̀rẹ̀ lórí òkú ọkùnrin kan tí wọn rí létí odò Omu tó wà ní Kelebe lójú ọna Oṣogbo sì Iragbiji, ìyẹn nipinlẹ Ọṣun.

Ọkàn lára àwọn aráàlú ni wọn lo o ri nnkan lórí odò náà, tó sì ro pe igi lásán ni, ìgbà tí wọn lo o sunmọ odò náà lo rí í pé òkú èèyàn ni, tó ń min lórí odò náà. 

Ìdí re e tó fi pariwo síta wí pé káwọn èèyàn wa a wo nnkan tòun rí, tó sì jẹ pe ko pẹ táwọn èèyàn fi debẹ. 


A gbọ pé ara ọkùnrin náà kò yà kò tó o di pé wọn ba òkú rẹ lórí omi. 

Àwọn ọlọpaa agbegbe Iludun là gbọ pé wọn padà gbé òkú náà lọ sí mọṣuari, tí wọn lẹru tí ń bá ọpọ àwọn èèyàn lágbègbè náà báyìí. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI