KAYEEFI ŃLÁ! WỌN YẸYẸ GBAJUMỌ KỌMIṢANNA ỌṢUN NITA GBANGBA, LO BÁ FIBINU SỌ̀RỌ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, April 12, 2020

KAYEEFI ŃLÁ! WỌN YẸYẸ GBAJUMỌ KỌMIṢANNA ỌṢUN NITA GBANGBA, LO BÁ FIBINU SỌ̀RỌ̀


Ọsẹ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ ẹ lo tán yìí kò dẹrun rárá fún Kọmiṣanna fọrọ àwọn obìnrin àti ìfẹ́ aráàlú {Women and Social Affairs} nipinlẹ Ọṣun, Ọnọrebu {Arábìnrin} Olubukọla Ọlabọọpo lórí bí àwọn òṣìṣẹ́ eleto ìlera ṣe yẹyẹ rẹ níta gbangba. 

Kò sí nǹkan méjì tí wọn loo fà á bí kò ṣe ti ẹsun aṣeju tí wọn fi kan án. 

Ọsibitu Ladoke Akintọla, ìyẹn Ladoke Akintola University of Technology Teaching Hospital (LAUTECH) to wá n'ilu Oṣogbo niṣẹlẹ náà tí wáyé laipẹ yìí. 

Gẹ́gẹ́ b'AWIKONKO ṣe gbọ, wọn ní obìnrin kan, Kafayat Adetunji tó bẹ somi láti gba ẹmi ara rẹ nítorí pé ebi tó ń pá a ní Kọmiṣanna náà lọọ wo l'ọsibitu pẹ̀lú àwọn amugbalẹgbẹ rẹ. 

Lẹ́yìn tí wọn ní Olubukọla Ọlabọọpo tí bá obìnrin náà sọ̀rọ̀ tán, tó sì tún ti gbé oṣuba káre fáwọn dọkita àtàwọn nọọsi tí wọn ń tọju ẹ ní wọn lo tún gbìyànjú láti bá a yà fọto.

Ibi tí wọn lo tí ń yà fọto yìí làwọn nọọsi tí lọọ bá a pé kò dawọ fọto náà dúró, àti pé ó lewu fún Arábìnrin tó ṣì ń gba itọju lọ́wọ́ yìí láti máa gbé e sórí ìkànnì ayélujára káàkiri.

Eyi ni wọn loo bí Ọlabọọpo àtàwọn amugbalẹgbẹ rẹ nínú tí wọn sì sọ ọrọ náà di ariwo, kò dá tí wọn làwọn amugbalẹgbẹ Kọmiṣanna náà kọjú ìjà sáwọn nọọsi yìí. 

Fún bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí là gbọ pé wọn fi fà ọ̀rọ̀ náà kò tó o di pé kọmiṣanna àtàwọn èèyàn rẹ bínú kúrò nibẹ. 

A gbọ pé bó ṣe kúrò nibẹ lo tí f'iṣẹlẹ náà tó Gomina Oyetọla létí, kò dá, tó tún gbà orí ìkànnì ayélujára tí fesibuuku rẹ lọ láti lọ fi aidunnu rẹ hàn nípa bí wọn ṣe yẹyẹ rẹ, tó sì tún ní wọn ba ẹ̀rọ ayaworan òun àti fóònù amugbalẹgbẹ òun jẹ́. 

Ohun tó kọ sórí fesibuuku rẹ ni pé:

"Mo wá ní ọsibitu LAUTECH láti ṣabẹwo sì obìnrin kan tó bẹ sínú odò láti gba ẹmi ara rẹ. Ìyàlẹ́nu lo jẹ́ fún mi pé ṣe làwọn òṣìṣẹ́ ọsibitu náà dojú tí èmi àtàwọn tá a jọ lọ.

"Ọkàn lára àwọn dọkita ọsibitu náà, Dọkita Iṣọla tí ẹ̀ka tó ń yẹ ọpọlọ wo já ẹ̀rọ ayaworan mi àti fóònù amugbalẹgbẹ mi gba, ó sì fọ wọn mọ́lẹ̀. Pẹ̀lú ìtìjú là fi kúrò nibẹ."

Bi obìnrin náà ṣe kọ ọ̀rọ̀ yìí tán làwọn èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ si í pín ín káàkiri, tó sì di àríyànjiyàn laarin awọn aráàlú náà, kò dá táwọn èèyàn tún ń sọ̀rọ̀ burúkú sáwọn òṣìṣẹ́ ọsibitu náà pé nnkan ti wọn se kú díẹ̀ kaato. 

Lójú ẹsẹ ti ọ̀rọ̀ yìí tí jáde síta, làwọn alaṣẹ ọsibitu náà tí gbé atẹjade síta wí pé ọ̀rọ̀ kò rí bí Kọmiṣanna náà ṣe kọ ọ sórí ayélujára. 

Atẹjade náà tí agbẹnusọ ọsibitu náà, Dọkita Ayọdele Adeyẹmọ fọwọ́ sì lo tí sọ pé lẹ́yìn igbimọ táwọn alaṣẹ yàn láti tọpinpin nnkan tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni wọn ti sọ pé Kọmiṣanna náà ṣe aṣeju lo fà á, àti pé wọn kò bá ẹ̀rọ ayaworan tàbí fóònù kankan jẹ́.

Ó ní kọmiṣanna náà kò tẹ́lẹ̀ àwọn òfin àti ìlànà tí wọn fi ń dáàbò bo àwọn aláìsàn l'ọsibitu, táwọn òṣìṣẹ́ ọsibitu yìí sí kilọ fún un, ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé ṣe ló sọ ọ dija mọ wọn lọ́wọ́.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI