Béèyàn bá rí DSP Ọpalọla Yẹmisi Ọlawọyin tí ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ṣẹ̀ṣẹ̀ kéde síta gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ wọn, iṣẹ náà yóò wù pupọ àwọn obìnrin láti ṣe.
Àwọ-málèlọ ni Ọpalọla Yẹmisi fáwọn tó bá rí í, pẹ̀lú bo ṣé pupa bí òyìnbó aláwọ̀ funfun, tí eyín ẹnu rẹ sì funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú.
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ, DSP Ọpalọla Yẹmisi, ọmọ bibi ìlú Ogbomọṣọ, ipinlẹ Ọ̀yọ́ náà lo gba iṣẹ lọ́wọ́ CSP Fọlaṣade Odoro tòun wá nibẹ tẹ́lẹ̀.
Fasiti ìlú Èkó ni Ọpalọla Yẹmisi tí kẹ́kọ̀ọ́ gboyè {B.Sc} nípa imọ ẹ̀kọ́ nípa àgbẹ̀ àti ọgbin, tó sì tún tẹsiwaju ni fasiti ìlú Ìbàdàn, níbi tó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè {M.Sc} nípa bí a ṣe ń yanjú aawọ láwùjọ, ìyẹn Peace and Conflicts Studies.
Ọjọ́ kinni oṣù kẹrin ọdún 1999 ni obìnrin arẹwà yìí gbà iṣẹ ọlọpaa, tó sì ti ṣíṣẹ káàkiri onírúurú ẹ̀ka nínú iṣẹ náà, lára wọn sì ni: Head of Police Departments and Formations; Human Rights Desk Officer; SIB Operative; Administrative Officer; ati Divisional Crime Officer.
Iyaale ilé ni Ọpalọla Yẹmisi, to sì ti bímọ ọkùnrin àti obìnrin fún ọkọ rẹ.
Fawọn to bá fẹ́ ẹ pé obìnrin náà, ó nọ́mbà 08067788119 ni wọn lé pé ẹ sì.
No comments:
Post a Comment