ÌKỌLÙ ÀWỌN ADIGUNJALE: ỌGA VGN N'IPINLẸ OGUN F'ỌKAN ÀWỌN ARA AGBEGBE IFỌ BALẸ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, April 12, 2020

ÌKỌLÙ ÀWỌN ADIGUNJALE: ỌGA VGN N'IPINLẸ OGUN F'ỌKAN ÀWỌN ARA AGBEGBE IFỌ BALẸ̀


Ọga àgbà fún ẹgbẹ́ Fijilante, ìyẹn VGN nipinlẹ Ogun, Kọmanda Ọlanrewaju Adedoyin tí fi dá gbogbo àwọn olùgbé ipinlẹ náà, paapaa àwọn ará agbegbe Ifọ wí pé kò tún ní í sì nnkan tó ń jẹ idigunjale tàbí jagidijagan mọ.

Adedoyin sọ pé gbogbo wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ láti bí ọsẹ méjì sẹ́yìn tí dohun ìgbàgbé nítorí pé àwọn tí dìde ogún sì gbogbo àwọn ọ̀daràn pátápátá. 

Fawọn to bá mọ bí nnkan ṣe ń lọ dáadáa nipinlẹ Ogun lásìkò yìí, wọn a mọ pe látìgbà tí ìjọba àpapọ̀ tí kéde konilegbele làwọn ọmọ ẹgbẹ́ okunkun àtàwọn adigunjale tí yawọ àwọn àgbègbè tó wà n'Ifọ títí di Ọta tí wọn sì ń jawọn èèyàn lólè. 


Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ni wọn ti fi ṣòfò dànù látìgbà tí wàhálà náà tí bẹ̀rẹ̀, táwọn ileeṣẹ eleto ààbò sì ti dìde ogún sì wọn. 

Lónìí ní Kọmanda Adedoyin de àwọn àgbègbè bí í Temidire, Greenland, Ifẹsowapọ, Ọrẹmeji ati Pakoto, níbi tó ti lọọ fọkàn àwọn aráàlú balẹ wí pé wàhálà tí wọn ń koju tí dópin báyìí.

Ọkùnrin náà là gbọ pé ó tún kọ àwọn èèyàn làwọn nnkan ti wọn lé ṣe lórí ààbò ara wọn, àti pàápàá bo tún ṣe sọ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn tí wá káàkiri láti dáàbò bo èmi àti dúkìá tó jẹ́ wọn lógún.













No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI