Ṣénkẹn báyìí ni inu gbogbo àwọn ará ìjọba ìbílẹ̀ Ilọrin East ń dùn báyìí lórí bijọba ṣe bẹ̀rẹ̀ àtúnṣe òpópónà kan tí wọn lo tí ń fìyà jẹ àwọn aráàlú náà tipẹ.
Òpópónà tí ẹ ń wo àwọn àwòrán rẹ yìí ló wà ladojukọ ilé alaga ìjọba ìbílẹ̀ Ilọrin East tẹle, Ọnọrebu Bibire Ajape tí wọn tún ń pè ní Barrywhite.
AWIKONKO gbọ́ pé ó ti pẹ tí òpópónà yìí tí ń dá wọn láàmú lágbègbè náà, ṣùgbọ́n láti mú ìlérí rẹ ṣe, ìjọba ipinlẹ náà tí pàṣẹ wí pé káwọn agbaṣẹṣe tí wọn mojuto òpópónà lọ ọ ṣe àtúnṣe lórí ọ̀nà náà fún ìgbádùn àwọn aráàlú.
No comments:
Post a Comment