Ìjọba ipinlẹ Kwara tí fìdí rẹ múlẹ̀ wí pé ohun yóò túbọ̀ máa rí sí ìgbé-ayé ara-ọtọ fáwọn aráàlú, èyí tí yóò jẹ ki wọn túbọ̀ máa jẹ mudun-mudun eto òṣèlú awaarawa, ìyẹn ìjọba alagbada.
Lónìí ni Gomina ipinlẹ náà, AbdulRahman Abdulrazaq sọ̀rọ̀ náà jáde láti fi dá gbogbo aráàlú lójú pé kí wọn lọọ fọkàn ara wọn balẹ nítorí pé asiko ìgbádùn tí de báyìí.
Nígbà tó ń gba ẹnu Kọmiṣanna fọrọ irinna àti iṣẹ ṣíṣe, Onimọ-ẹrọ Suleiman Rotimi sọ̀rọ̀ lo tí ni igbayegbadun àwọn aráàlú ipinlẹ náà lo jẹ́ wọn lógún.
Ibi ìpàdé tó wáyé pẹ̀lú àwọn olóyè ẹgbẹ́ ọlòkada, igbimọ oluranwọ fún àrùn COVID-19 àtàwọn alẹnulọrọ nipinlẹ náà, èyí tó wáyé lónìí l'ọrọ náà tí jade.
O ni kò sí ọrọ ẹlẹyamẹya ninu ohun tijọba ni lọ́kàn láti ṣe fún aráàlú, pàápàá lásìkò konilegbele yìí, nítorí pé ìjọba mọ adojukọ táwọn èèyàn ń koju.
Suleiman dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn aráàlú fún aduroti wọn àti bí wọn ṣe ń tẹle àwọn òfin àti ìlànà konilegbele yìí, pàápàá lọ́nà láti dẹkùn itankalẹ àrùn koronafairọs.
No comments:
Post a Comment