ÌBOMÚ ALÁṢỌ KÒ LÉ DÈNÀ ÀRÙN KORONAFAIRỌỌSI - NAFDAC PARIWO SÍTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, April 28, 2020

ÌBOMÚ ALÁṢỌ KÒ LÉ DÈNÀ ÀRÙN KORONAFAIRỌỌSI - NAFDAC PARIWO SÍTA


Ajọ to n ri si iṣakoso ounjẹ ati oogun lilo, ìyẹn NAFDAC ti pariwo síta fáwọn ọmọ Nàìjíríà káàkiri wí pé àwọn ibomu ti wọn ba ti fi aṣọ ran ko le dena aarun koronafairọọsi.

Ọjọ́ Ajé, ìyẹn Mọnde àná ni ajọ NAFDAC ṣalaye lori ìkànnì ayélujára rẹ pe o ṣeé ṣe ki ibomu ti wọn fi aṣọ ṣe mu adinku ba itankalẹ aarun COVID-19, ṣùgbọ́n ko le dena rẹ lailai.

Ajọ naa sọ pe o yẹ ki awọn eeyan maa fọ iru ibomu bẹẹ lojoojumọ lẹyin ti wọn ba ti loo tan.

Èyí tó tún burú ju nibẹ ni bí àjọ náà tún ṣe ṣalaye wi pe fifọ ibomu ti wọn fi aṣọ ṣe yoo tubọ ṣakoba lati ma lagbara lati dena aarun koronafairọọsi.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI