GBOGBO ỌMỌ NÀÌJÍRÍÀ LA MÁA TỌJU PÁTÁPÁTÁ - BUHARI ṢÈLÉRÍ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, April 12, 2020

GBOGBO ỌMỌ NÀÌJÍRÍÀ LA MÁA TỌJU PÁTÁPÁTÁ - BUHARI ṢÈLÉRÍ


Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari tí ni káwọn èèyàn fọkànbalẹ̀ nítorí pé gbogbo wọn pátápátá ní wọn máa jẹ mudunmudun ẹtọ iṣejọba awaarawa, pàápàá lásìkò yìí. 

Buhari lo sọ̀rọ̀ yìí nínú atẹjade tí agbẹnusọ rẹ, Garba Shehu fi síta lọ́jọ́ Satide àná, èyí tí ẹ̀da rẹ tẹ AWIKONKO lọ́wọ́ lónìí.

Nibẹ lo tí dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè yìí fún àdúrà tí wọn láti tẹle àwọn òfin àti ìlànà konilegbele láti dẹ́kun itankalẹ àrùn COVID-19 tó ṣekú pawọn èèyàn káàkiri àgbáyé. 

Ó ní òun mọ ìyà tí gbogbo àwọn tó dibo fún wọn ń lá kọjá lásìkò yìí, táwọn sì gbọ́dọ̀ dúpẹ́ fún ìfaradà wọn, àtàwọn tó jẹ́ pé inú iṣẹ ojoojumọ ni wọn ti ń rí owó jẹun. Ó ní síbẹ̀, kò sì nnkan táwọn fẹ ẹ ṣe ju káwọn yàgò fáwọn nnkan tó lè túbọ̀ tan àrùn náà kọjá sísọ lọ. 

Bẹẹ lo tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ náà pé kani ọ̀nà àbáyọ mi in wá tó yàtọ̀ sí báwọn onimọ-ijinlẹ àtàwọn oníṣègùn oyinbo ṣe sọ fún wa nipa bí a ṣe lè dẹ́kun àrùn yìí, ó ni kò bá dára, ṣùgbọ́n kò sí nnkan táwọn fẹ́ ẹ ṣe ju káwọn tẹle amọran wọn, pàápàá nígbà tí kò ti í sì ogún ìtọ́jú fún àrùn náà. 

Ó wà fi kún un pé ìjọba ti pàṣẹ wí pé kí wọn kò oúnjẹ síta lọ̀pọ-yanturu fáwọn aráàlú, táwọn sì tún fi owó tí í lẹgbẹ káàkiri ìjọba ipinlẹ àti ibilẹ tó fi mọ orílẹ̀-èdè.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI