Lónìí tí í ṣe Satide Abamẹta ni isede ọlọjọ mẹ́rinla káàkiri orílẹ̀-èdè yìí tí ìjọba àpapọ̀ pàṣẹ rẹ lọsẹ tó kọjá bẹ̀rẹ̀ nipinlẹ Ogun.
Nínú ìwádìí AWIKONKO káàkiri àwọn àgbègbè mélòó kan n'ilu Abẹ́òkúta tó jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ náà là tí rí àwọn òpópónà tó dá pátápátá, kò dá tí eṣinṣin kò fò depodepo wípé èèyàn yóò rìn ín regberegbe.
Kí í ṣe pé ìjọba àpapọ̀ dee de pàṣẹ konilegbele, bí kò ṣe láti dẹkùn itankalẹ aarun àṣekupani tí Coronavirus tó ń jà rain-rain lagbaye.
Díẹ̀ re lára àwọn fọto bí ìlú Abẹ́òkúta ṣe ri
No comments:
Post a Comment