GBOGBO ẸNI TO BÁ DALẸ̀ YIN KO NI I N'ISINMI BÍI TÍ JUDASI - ALÁYỌ̀ SINGER - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, April 11, 2020

GBOGBO ẸNI TO BÁ DALẸ̀ YIN KO NI I N'ISINMI BÍI TÍ JUDASI - ALÁYỌ̀ SINGER


Gbajumọ olorin nnì tí ayé ń gba tiẹ̀ dáadáa lásìkò yìí, Ọgbẹni Ayọọla Akinọla Michael tọpọ àwọn èèyàn mọ sì Alayọ Melody Singer tí gbàdúrà fún gbogbo àwọn olólùfẹ́ ẹ pátápátá káàkiri àgbáyé wí pé gbogbo ẹni tó bá dalẹ wọn kò ní í nisinmi.

Káàkiri gbogbo orí ìkànnì ayélujára ni ilu mọ-ọn-ká olorin náà tí lo àǹfààní ayẹyẹ ọdún àjíǹde tó wà níta lásìkò fi kí àwọn olólùfẹ́ rẹ, tó sì tún gbàdúrà fún wọn.

Ninu ọrọ Alayọ Singer tó tún fi fọ́nrán orin kan tí í lẹgbẹ lo tí sọ pé bí Júdásì kò ṣe ní ìsinmi tó fi gbẹmi ara rẹ lẹ́yìn tó dalẹ Jésù náà ni gbogbo àwọn tó bá dalẹ àwọn olólùfẹ́ rẹ kò ní í nisinmi. 

Ó sọ pé "Lẹsẹkẹsẹ tí Júdásì Ísíkáríótù dalẹ Jésù, ó sọ àlàáfíà rẹ nù, kò sì nisinmi títí tó fi pokunso. Lónìí, mo pàṣẹ sínú ayé yín wí pé ẹnikẹ́ni tó bá dalẹ rẹ, kò ní í nisinmi títí tí yóò fi gba ìtìjú lórúkọ Jésù. 

"Mo gbàdúrà pé ayajọ ayẹyẹ àjíǹde Jésù yìí yóò bukun fún ìwọ àti ìdílé rẹ pẹ̀lú àlàáfíà, ìfẹ́ àti àṣeyọrí lórúkọ Jésù."


Siwaju sì í ní Alayọ Singer tún ti fi asiko náà pé gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ pé kí wọn pàdé òun lórí ìkànnì ayélujára tí Fesibuuku àti Insitagiraamu l'ọjọ Sande àti Mọnde bẹ̀rẹ̀ láti aago méjì ọ̀sán sì mẹ́fà irọlẹ.




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI