GBAJUMỌ ONIROYIN, SAHEED OJUBANIRẸ Ń ṢAYẸYẸ ỌJỌ́ ÌBÍ OGÓJÌ ỌDÚN LÓNÌÍ, BẸ́Ẹ̀ LO TÚN SỌ BÍ COVID-19 ṢE ṢÀKÓBÁ FÚN IPALEMỌ AYẸYẸ NAA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, April 14, 2020

GBAJUMỌ ONIROYIN, SAHEED OJUBANIRẸ Ń ṢAYẸYẸ ỌJỌ́ ÌBÍ OGÓJÌ ỌDÚN LÓNÌÍ, BẸ́Ẹ̀ LO TÚN SỌ BÍ COVID-19 ṢE ṢÀKÓBÁ FÚN IPALEMỌ AYẸYẸ NAA


Òní l'ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ìlú-mọ-ń-ka oniroyin nnì, Saheed Ojubanirẹ, táwọn olólùfẹ́ rẹ káàkiri àgbáyé sì ti ń kí kú oriire, pàápàá bo tune ṣe jẹ́ pé ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ogójì ọdún lo ń ṣe. 

Fawọn to bá mọ oore Ọlọ́run, wọn a mọ pe oore ọfẹ ńlá ni kí èèyàn pé ogójì ọdún láyé nínú ìlera pípé àti àlàáfíà.

Ohun tí àwọn èèyàn sì máa ń sọ ní pe igbe ayé bẹ̀rẹ̀ láti ogójì ọdún 


Gbajumọ oniroyin náà tó tún jẹ́ agbẹnusọ fún gbajugbaja olorin Fuji nnì, Alaaji Ṣefiu Àlàó, ìyẹn Baba Oko lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn nígbà tó ń fi imọriri oore Ọlọ́run hàn lo tí lòun kò lè ṣàì dúpẹ́ fún oore ńlá náà. 

O ni bí i bá a ṣe tí àrùn COVID-19 tó gbà ìlú lásìkò yìí ni, ọjọ́ Sande ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù yìí lòun ni í lọkan láti ṣe ayẹyẹ náà ni ńlá, tòun yóò fi ilé pò ọtí, tòun yóò sì tún fi ọ̀nà roka. 


Síbẹ̀, ó ní konilegbele tó ń lọ lọ́wọ́ yìí tí mú káwọn yẹ ìpinnu ayẹyẹ náà, táwọn sì ti sún un síwájú di ọjọ́ mi-ín táwọn kò ti í mọ. 

AWIKONKO gbọ pé inú oṣù kejì ọdún yìí ni Saheed Ojubanirẹ bẹ̀rẹ̀ ipalẹmọ eto ayẹyẹ náà, tó sì tún tá aṣọ ẹgbẹ́jọdá fáwọn olólùfẹ́ rẹ.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI