"Mi o jẹbi pẹlu alaye, ẹ f'oju aanu wo mi" lọrọ ẹbẹ to n tẹnu Peter Alateke jade nile ẹjọ Majisireeti to f'ikalẹ s'ilu Ọwọ, ipinlẹ Ondo laipẹ yii lori ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan an.
Ijọba ipinlẹ Ondo lo wọ Peter lọ si kọọtu naa n'igba ti wọn f'ẹsun kan an wi pe o ja ibale ọmọdebinrin, ọmọdun mẹrindinlogun kan ta a f'orukọ bo laṣiri.
AWIKONKO gbọ pe ohun to jẹ ki ọrọ Peter ti wọn l'oun ni oludasilẹ ṣọọṣi kan to wa lagbegbe Ẹhinogbe n'ilu Ọwọ ni bi wọn ṣe sọ pe itọju ni Peter loun fẹẹ ṣe fun ọmọ naa.
Ọmọdebinrin naa ti wọn sọ pe lojiji ni aisan warapa de si i lara, ti wọn si mu u lọ si ṣọọṣi Peter to gbajumọ daadaa lati ba wọn gbadura fun un, lai mọ pe ṣe lo ma maa ba a laṣepọ.
N'igba t'aṣiri ma a tu, wọn ni ṣe l'ọmọ naa ṣa dede bẹrẹ aisan, ti wọn si rii pe oju ara rẹ lo n ṣomi ṣororo. Idi re e ti wọn fi beere ọrọ lọwọ ẹ, to si jẹwọ pe Peter lo fipa ba oun laṣepọ, ati pe ki i ṣe igba kan ṣoṣo lo ṣe kini naa fóun.
Idi re e ti wọn fi f'oju Peter ba ile ẹjọ lori ẹsun kan ṣoṣo to ni i ṣe pẹlu ifipabanilopọ kan an, t'oun naa si jẹwọ pe loootọ ni, ati pe iṣẹ eṣuni.
Onidajọ Olubunmi Dosumu nigba to n sọrọ sọ pe oun yoo fun Peter lanfaani lati gba beeli ara rẹ l'ọwọ ti ko din ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta {500,000} naira pẹlu oniduro meji ti wọn je oludasilẹ ijọ, ti wọn si tun jẹ ọga agba labẹ ijọba, to si sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kejidinlogun oṣu kẹfa ọdun yii.
No comments:
Post a Comment