EYI NI BÍ ÀRÙN KORONAFAIRỌỌSI ṢE LÈ ÒGÚN-MAJẸẸKI, AGBA ÒṢERÉ TÍÁTÀ KÚRÒ L'ỌSIBITU UCH N'IBADAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, April 20, 2020

EYI NI BÍ ÀRÙN KORONAFAIRỌỌSI ṢE LÈ ÒGÚN-MAJẸẸKI, AGBA ÒṢERÉ TÍÁTÀ KÚRÒ L'ỌSIBITU UCH N'IBADAN


Ogun Majek, òṣèré tíátà ní iléèwòsàn UCH lòun ti ń gba ìtọ́jú kí àrùn Coronavirus tó wọ̀lú

Eekan oṣere tiata ati sinima lorilẹede Naijiria, Gbọlagade Akinpẹlu ti ọpọ mọ si Ogun Majek to wa ni idubulẹ aisan lọwọ bayii ti ṣalaye pe aisan oun ko ṣẹṣẹ bẹrẹ ati pe ọpọlọpọ asiko loun lo ni ileewosan nla UCH nibi ti oun ti n gba itọju.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, lori ẹrọ ibanisọrọ, alagba Ogun Majek ṣe e lalaye pe ajakalẹ arun Coronavirus to de lo gbe oun kuro ni ileewosan naa.

O fi kun pe awọn ẹgbẹ oṣere lorilẹede Naijiria, TAMPAN ti da si ọrọ oun wọn si ti n gbe igbesẹ to yẹ lori rẹ.

O ni ọkan imoore loun ni fun ẹgbẹ naa atawọn alaṣẹ rẹ fun bi wọn ko ṣe da oun da wahala naa.

Ni ọjọ Aiku ni ọkan lara awọn oṣere sinima lorilẹede Naijiria,

Ọkan lára àwọn gbajumọ osere tiata lọkunrin lédè Yoruba, Gbolagadé Akinpelu, tí gbogbo èèyàn mọ sì Ogun Majek, n ṣàìsàn báyìí, to sì lè pupọ.

Bákan náà ni Ogun Majek nílò iranlọwọ owó láti fi tọju ara rẹ, ko le bọ lọwọ àìsàn náà.

Gbajumọ osere tiata lobinrin, Foluke Daramola lo fi idi ọ̀rọ̀ yii mulẹ lójú opo Instagram rẹ pẹlu àfikún pe, Ogun Majek nílò owó láti fi ṣe itọju ara rẹ.

Àwọn ọ̀nà tí ẹ le fi dun ara yín nínú lásìkò yìí
Bákan náà lo fikùn pé, àwọn èèkàn ọmọ ẹgbẹ́ osere tiata kan náà tí ń sá ipa wọn láti ṣe itọju Ogun Majek, àmọ́ ìyànjú wọn yìí kò tíì tó láti wo àìsàn baba náà sàn pátápátá.

"Àìsàn baba Ogun Majek le pupọ, tó sì jẹ ara àwọn àìsàn tó maa n gbẹmi ẹni ní. Baba Ogun Majek nílò ìranwọ owó yín lásìkò yìí, kí wọn leè gbádùn padà".

Daramola wá ń ké sí àwọn ẹlẹyinju àánú ọmọ Naijiria, lati dìde ìranwọ fún Ogun Majek ko lee ri owo to to owó láti fi ṣe ìtọ́jú ara rẹ nílé ìwòsàn, ó ní káwọn aráàlú dakun, ogún Majek nílò iranlọwọ wọn.

"Àjọ aláàánú Para Foundation ń rawọ ẹ̀bẹ̀ si ọkàn àánú yín láti ṣètò iranlọwọ fún baba Ogun Majek, kò lè e bọ nínú ipò ikaanu tó wa.

Foluke ni iye kíyè táwọn ara ilu bá ní yóò seranwọ láti gba ẹ̀mí Ogun Majek la, àwọn ko si fẹ ki ẹ̀mí rẹ bọ lásìkò yìí tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ pàdánù Pa Kasumu.

Lati: BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI