Ilu mọ-ọn-ká àgbà òṣèlú lorilẹ-ede èdè Nàìjíríà, pàápàá nipinlẹ Ogun, Ọmọba Gboyega Nasir Isiaka tí gba gbogbo àwọn ọmọ orilẹ-èdè yìí lamọran wí pé kí wọn ní ìfaradà, kí wọn sì gba kamu lásìkò yìí, nítorí pé fún ìgbà díẹ̀ ni.
Ọmọba Gboyega Isiaka t'ọpọ tún mọ sì GNI lo sọ̀rọ̀ yìí lórí ìkànnì ibara-ẹni-sọrọ, ìyẹn WhatsApp táwọn ọmọ Ìpínlẹ̀ Ogun tí wọn pé ní Ogun State Watch lónìí, ìyẹn lásìkò tí wọn béèrè oríṣiríṣi ìbéèrè lọ́wọ́ ẹ.
GNI, oludije sípò gómìnà ipinlẹ Ogun lẹẹmẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ẹni to tí kò ipa ribiribi tí kò lafiwe láwùjọ sọ pé ìṣòro tó ń dojú kọ orilẹ-èdè Nàìjíríà lónìí, aarun tó ń ṣe gbogbo àgbáyé lo ń ṣe.
Ogbontarigi olóṣèlú náà sọ pé gbogbo ìnira, ìyà táwọn ọmọ Nàìjíríà, pàápàá àwọn tó kú díẹ̀ kaato fún lo ye òun yekeyeke àti pé ìyà kan ṣoṣo náà tó ń jẹ aláìní náà lo ń bá olówó fínra, tó fi mọ àwọn olóṣèlú.
Ẹ ó rántí pé ní kété tí aarun koronafairọs bẹ̀rẹ̀ si í gbilẹ sì ni Nàìjíríà, ní Ààrẹ Muhammadu Buhari tí pàṣẹ konilegbele fún ọjọ́ mẹ́rìnlá gbáko láti dẹ́kun itankalẹ aarun náà.
O jẹ kò ye àwọn èèyàn pé nnkan ti pupọ wọn kò mọ nípa aarun koronafairọs yìí ni pé kí í ṣe ìjọba tàbí aráàlú lo dá aarun yìí silẹ, bí kò ṣe pé pupọ àwọn aríran ni wọn ti rí ọjọ iwájú pé nnkan báyìí ń bọ̀.
Bẹẹ lo tún fi kú ọ̀rọ̀ rẹ wí pé káwọn èèyàn rọra máa lo àwọn nǹkan tó bá wá ní ikawọ wọn, bí í oúnjẹ kí asiko náà tó o pé. Ó rawọ ẹ̀bẹ̀ sijọba wí pé kí wọn túbọ̀ na ọwọ àánú sáwọn tó kú díẹ̀ kaato fún, gẹgẹ boun náà tí bẹ̀rẹ̀ igbesẹ yìí.
No comments:
Post a Comment