Yorùbá ní tí iná bá kú, á fi eérú bo ojú, bí ọ̀gẹ̀dẹ̀ bá kú, yóò fi ọmọ rẹ rọ́pò, bí aladi kò bá sí nílé, ọmọ wọn lo ń jogún ẹbu.
Bẹẹ ni ọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú àwọn àgbà ọjẹ òṣèré tíátà kan nílẹ̀ Yorùbá, tí wọ́n fi iṣẹ oojọ tí wọn yan láàyò lé ọmọ bibi wọn lọ́wọ́ láti jogún rẹ.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọpọ àwọn àgbà òṣèré tíátà náà tí jáde láyé, tí àwọn míràn nínú wọn sì wà lókè eepẹ, síbẹ̀ àwọn ọmọ tí wọn fi iṣẹ lé lọ́wọ́, sì ń ṣe ilédè lọ lẹ́yìn wọn lagbo tíátà.
Àwọn Òṣèré tíátà tó jogún isẹ lọ́wọ́ òbí wọn:
Adelaja Ogunde:
Adelaja, tíi ṣe àgbà osere tíátà lọ jẹ ọmọ bibi oludasilẹ ère tíátà ni èdè Yorùbá, Herbert Adedeji Ogunde.
Ìlú Ọsọsa lágbègbè Rẹmọ nipinlẹ Ogun ni àwọn Ogunde ti wá.
Bí Herbert Ogunde tilẹ̀ tí dagbere faye, sibẹ, Adelaja, to jọ baba rẹ bíi imumu, sì ń di odi mu lọ lagbo ere tíátà.
Peju àti Yomi Ogunmola:
Àwọn gbajumọ òṣèré tíátà yìí, tí wọn jẹ obinrin àti ọkunrin, ló jogún isẹ tíátà lọ́dọ̀ bàbá àti iya wọn, olóògbé Kola Ogunmola àti ìyàwó rẹ.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Yomi Ogunmola tí di ará ilẹ̀, sibẹ, Peju sì wà láyé, tó ń dá bíi ẹdun, rọ bíi oowe lagbo tíátà, ìlú Òkè Imesi nipinlẹ Ekiti, si ni ilu abinibi wọn.
Gbajumọ òṣèré tíátà miran, Sunday Omobolanle, tí gbogbo èèyàn mọ si Pappy Luwẹ, sì ló fẹ́ Peju Ogunmola bíi aya.
Sunkanmi Omobolanle:
Àkọ́bí Sunday Omobolanle, taa mọ sì Aluwẹ, ni Ṣunkanmi jẹ, tó si jogún eré tíátà lọdọ bàbá rẹ̀.
Sunkanmi, to wá láti ìlú Ilora nipinlẹ Oyo pẹlu baba rẹ, jẹ ọkan lára àwon ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ gbajumọ amuludun lagbo tíátà lọ́wọ́ lọ́wọ́.
Femi, Tope àti Biola Adebayo:
Femi, Tope àti Biola Adebayo, ti wọn ń ṣe gudugudu méje àti yà yà mẹ́fà lagbo tíátà báyìí, ní wọn jẹ ọmọ bibi àgbà ọjẹ kan lagbo ere tíátà, Adebayo Salami, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ si Ọga Bello.
Láàrin àwọn ọmọ Ọga Bello mẹtẹẹta to ń ṣe eré náà, Biola nìkan ni obìnrin, bí erin baba wọn sì ṣe ń fọn, náà ni erin àwọn ọmọ rẹ yìí ń fọn lagbo tíátà.
Àwọn ọmọ ọga Bello náà, ti wọn wa lati ilu Ilorin, ní wọn ti kẹ́kọ̀ọ́ gba òye imọ ìjìnlẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ fasiti, kí wọn to jogún isẹ ti baba wọn ń ṣe, kódà agbẹjọro ni Femi, tíì ṣe àgbà wọn.
Sola àti Abidemi Kosoko:
Sola àti Abidemi Kosoko, tí àwọn méjèèjì jẹ gbajumọ osere lobinrin ni wọn jogún isẹ náà lọ́wọ́ bàbá wọn, Jide Kosoko, tíì ṣe àgbà ọjẹ osere tíátà.
Ọ̀pọ̀ ere itage, sinima àti fíìmù àgbéléwò si ni bàbá àti àwọn ọmọbìnrin arẹwà rẹ méjèèjì, tí wọn jẹ ọmọ ọba nìlú Èkó, tí kopa ninu rẹ.
Kunle, Aremu Gabriel àti Mojisola Afolayan:
Àwọn akínkanjú osere tíátà yìí, Kunle Afolayan, Aremu Afolayan, Gabriel Afolayan àti Mojisola Afolayan ni wọn jẹ ọmọ bibi inú gbajumọ àgbà ọjẹ osere tíátà kan tó ti di olóògbé, Adeyemi Afolayan, tí àwọn èèyàn tún ń pe ni Ade Love.
Ìlú Agbamu, nipinlẹ Kwara si ní àwọn Afolayan yìí ti wa.
Lẹ́yìn tí Ade Love papoda tán, ní àwọn ọmọ bibi rẹ mẹ́rin náà, tí mẹta nínú wọn jẹ ọkùnrin nígbà tí Mojisola nìkan jẹ obinrin, jogún isẹ baba wọn, tíì ṣe ère tíátà.
Kò sí sì ẹni tó leè fi ọwọ rọ àwọn ọmọ Ade Love sẹ́yìn nínú isẹ ti wọn yàn láàyò náà, nítorí bí wọn tí ń ṣe ere tíátà ni èdè Yorùbá, naa ni wọn tún ń ṣe é ní èdè oloyinbo.
Kódà, gbajumọ osere tíátà míì, Razak Olayiwola, tí wọn tún ń pè ní Ojopagogo, lo fẹ́ Mojisola ọmọ Adeyemi Afolayan ni ìyàwó, tí àwọn méjèèjì sì tún dijọ ń ṣe iṣẹ́ tíátà papọ.
Muka, Murphy àti Lasun Ray Eyiwunmi:
Àwọn ilumọọka osere tíátà mẹta yìí ni wọn jogún isẹ náà lọ́wọ́ àwọn òbí wọn, olóògbé Ray Eyiwunmi àti aya rẹ, ìyá Ray.
Àwọn akọni mẹta lagbo tíátà náà, tí wọn wa lati ìjọba ìbílẹ̀ Irepodun nipinlẹ Kwara, ni wọ́n ko leè kọ iyán wọn kéré lagbo osere tíátà ni èdè Yorùbá.
Segun Ogungbe:
Segun Ogungbé lọ jogún isẹ tíátà láti ọdọ bàbà rẹ , alàgbà olóògbé Akin Ogungbe, tó wá láti ilu Abeokuta nipinlẹ Ogun.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé onirese Baba rẹ kò fín igbá mọ, tó sì ti jáde láyé, síbẹ̀, Segun kò jẹ ki igbá tí bàbá rẹ̀ fín silẹ parun, to sì ń ba ere tíátà lọ ní pẹrẹu.
Mide Martins:
Mide Martins ni ọmọbìnrin gbajumọ osere olóògbé Funmi Martins jẹ, ní kete tí Funmi si fi ilẹ ṣe aṣọ bora, ní Mide, ọmọ rẹ gbé igba ere tíátà tó fi silẹ, to si ti di ilumọọka.
Kódà, osere tíátà lọkunrin miran, Afeez Abiodun, tí àwọn èèyàn mọ si Afeez Ọwọ nínú eré tíátà, ní Mide fẹ ni ọkọ, tí àwọn méjèèjì sì jọ jẹ gbajumọ osere ni èdè Yorùbá.
Azeez Ijaduade:
Azeez ni ọmọkùnrin Dimeji Ijaduade, tíì ṣe ilumọọka osere tíátà láti Abeokuta.
Baba àti ọmọ si ni wọn jọ ń dabira lagbo ere tíátà báyìí bíi gbajumọ osere, ọmọdé kékeré si ni Azeez tí jogún ere tíátà lọ́wọ́ bàbá rẹ̀.
Samuel Olasehinde:
Samuel ni ọmọ bibi àgbà ọjẹ kan lagbo osere tíátà, Kayode Olasehinde, tí inagijẹ rẹ sì ń jẹ Ajirebi.
Láti ọmọ ọdún márùn-ún ni Samuel ti ń kopa ninu ere tíátà, tó sì ti jáde nílé ẹ̀kọ́ Fáṣítì Obafemi Awolowo n'ilu Ilé Ìfẹ́ báyìí.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé imọ nípa isẹ agbẹjọro ni Samuel kọ ní fasiti, síbẹ̀ ere tíátà tó jogún lọdọ baba rẹ, lo yàn ni ààyò.
Láti: BBC
No comments:
Post a Comment