Bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí, orin ọpẹ làwọn ara agbegbe Ifọ, Owode-Ijakọ, Jọju, Ijoko ati Àgbàdo n'ipinlẹ Ogun mú sẹnu báyìí pẹ̀lú bọ̀wọ̀ àwọn ọlọpaa ṣe tẹ àwọn afurasi ọ̀daràn tí kò dín ni méjìdínlógún tí wọn ń jawọn èèyàn lólè.
Lati bí oṣù mélòó kan sẹ́yìn là gbọ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tí ń kọjú ìjà síra wọn, èyí tí a gbọ pé ṣe ni wọn ń fi agbára hàn ara wọn.
Ọ̀pọ̀ ẹmi là gbọ pé wọn tí jabọ nínú ìkọlù yìí, tá a sì gbọ pé inú ibẹribojo àti aibalẹ-ọkan làwọn ara agbegbe naa n gbe.
Ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn là gbọ pé ọ̀rọ̀ náà tún kọjá ojú táwọn èèyàn fi ń wo ó, tó sì jẹ pe ṣe ni wọn tún ń lo àǹfààní náà láti fi jawọn èèyàn lólè, tí wọn ń fipá báwọn obìnrin láṣepọ káàkiri.
Idi re e táwọn ọlọpaa àtàwọn fijilante fi dìde láti daabo bo ẹ̀mí àwọn aráàlú, tí wọn sì gbógun ti àwọn èèyàn náà.
Lára àwọn tọwọ tẹ l'Owode-Ijakọ ni Ẹkunoye lucky, ọmọdun méjìlélógún; Badmus Sọdiq, ọmọdun mẹtadinlọgbọn; Ṣhowumi Fẹmi, ọmọdun mọkanlelogun; Adeagbo Adewumi, ọmọdun méjìlélógún ati Agboọla Fẹmi tòun jẹ́ ọmọdun mọkanlelogun.
Adekunle Ọkẹoye, ọmọdun mẹtalelogun là gbọ pé ọwọ tẹ lágbègbè ṣọọṣi Winner lójú ọna Idiroko tí wọn gba ìbọn ilewọ tuntun pẹ̀lú ọta ìbọn márùn-ún, àtàwọn oogu tí abẹnugọngọ lọ́wọ́ ẹ.
Sulaiman Ogunbiyi tí inagijẹ rẹ ń jẹ Absorver Federal, Saminu Adamu àti Nasiru Umar lọ́wọ́ palaba wọn segi lágbègbè Ararọmi ni Àgbàdo pẹ̀lú oogun abẹnugọngọ àti ìbòjú.
Ṣáájú asiko yìí là gbọ pé ọwọ tí kọ́kọ́ tẹ àwọn mẹ́wàá lágbègbè Ifọ, Kajọla àti Ososun nijọba ìbílẹ̀ Ifọ.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipínlẹ̀ Ogun, Kenneth Ebrimson tí pàṣẹ pé kí ẹka ileeṣẹ wọn tó ń rí sì ọ̀ràn àti olè jíjà túbọ̀ ṣe ìwádìí àwọn èèyàn náà, bẹ́ẹ̀ lo pàrọwà sáwọn aráàlú pé kí wọn fọkàn wọn balẹ nítorí pé àwọn ṣetan láti dáàbò bo wọn.
Bẹẹ lo ni kí wọn pé 08081770416 bí wọn ba kofiri àwọn ọ̀daràn lágbègbè wọn.
No comments:
Post a Comment