"Ko gbo, ko tọ, ko f'erigi jobi. Àṣẹ a pẹ, pẹ, pẹ, pẹ, pẹ, lẹ́nu. Wa ṣe 50, wa ṣe 60, wa ṣe 70, wa ṣe 80, wa ṣe 90, wa ṣe 100.. Ninu ọlá, àlàáfíà, ifọkanbalẹ, ayọ̀, idunnu, igbega ..."
Wọ̀nyí lọrọ àdúrà tí Oluwo tilu Iwo, Ọba Abdulrọsheed Adewale Akanbi, Telu kinni fi kí Eleguṣi tilu Ikate, Ọba Saheed Ademọla fún tí ayẹyẹ ọdún kẹwàá lórí ipò.
Ọba Oluwo sọ pé kò sẹni tòun tún fi inú tán láwùjọ àwọn lọbalọba, bí kò ṣe Ọba Saheed Ademọla, tó sì jẹ ọ̀rẹ́ òun timọtimọ tòun nigbagbọ nínú ẹ dáadáa.
Nínú ọ̀rọ̀ Oluwo lo tún ti sọ pé:
"O ti yà ara rẹ s'ọtọ láti jẹ alagbẹkẹle, olotitọ, atoofarati àti oluranwọ fún gbogbo èèyàn káàkiri. Opo téèyàn lè tọka sì ni ẹ, tó sì jẹ pe pupọ àwọn èèyàn ní wọn lé fi ẹ ṣe atitọkasi nípa iranlọwọ. Ìwọ kì í wo ohunkóhun kí ó tó o ṣàánú, tí ó sì tayọ kọjá àwọn akẹgbẹ rẹ.
"Bí ó ṣe ń ṣayẹyẹ ọdún kẹwàá lórí ìtẹ́ àwọn bàbà-ńlá rẹ lónìí ọjọ́ kẹtadinlọgbọn oṣù kẹrin ọdún 2020, erongba àti àdúrà mi ni pé, Olódùmarè yóò túbọ̀ máa rò ẹ lágbára láti ṣe ju ti tẹ́lẹ̀ lọ nípa kikopa rere láyé àwọn ẹ̀dá.
"Ibaṣepọ mi pẹ̀lú rẹ kò lẹgbẹ láwùjọ wá. Ọ̀pọ̀ ìgbà láti bẹ ara wa wo, mi ò sì fìgbà kan rí kabamọ làwọn àsikò tá a fi ń ṣe ọ̀rẹ́ torí pé ipa rere lo ń kó. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló gbìyànjú láti yà wá ṣùgbọ́n tó jẹ́ òfo ọjọ́ kejì ọjà. Aditu ni ibaṣepọ ọlọjọ-pipẹ wá jẹ lójú ọpọ, ṣùgbọ́n tó ye àwa yekeyeke.
"Àwọn ìrántí asiko tá a lo papọ láti fọrọjomitoro ọ̀rọ̀ ń jẹ iwuri. Ó ń wá ìlọsíwájú mi, bẹ́ẹ̀ lemi náà ń wá tiẹ̀. Èyí ni àpèjúwe kékeré nípa ajọṣepọ wá. Eleguṣi, ní gbogbo ìgbà àti síwájú sí í lo má máa gbádùn oore-ọfẹ àti àánú Ọlọ́run lórí ìtẹ́. Kò sí ọ̀tá tí yóò borí rẹ.
"Gẹgẹ bí a ṣe máa ń ṣe àti bí a ṣe ṣeé lọ́dún tó kọjá, àrùn koronafairọọsi kò lè di wá lọ́wọ́ láti jọ kí ara wa kú ayẹyẹ. Mo ti pèsè oúnjẹ aladidun láti fi ja aawẹ mi fún ìrántí ayẹyẹ yìí lónìí, pàápàá bo tún ṣe jẹ́ asiko aawẹ láti gbàdúrà fún ẹ, kí n sì wá ojurere gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń fẹ́ kó rí fún mi.
"A jọ máa ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún títí lai papọ ni. Adé náà yóò mọ wá lórí pẹpẹ fún ìgbà tí a bá fi wá láyé, láti máa fi mọ rírí Olódùmarè.
"Iṣẹdalẹ yóò túbọ̀ máa fà àlàáfíà, ìdùnnú, ẹmi gígùn àti iyepọ. Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ títí lai."
No comments:
Post a Comment