Lọ́jọ́ Ajé, Mọnde àná n'ijọba àpapọ̀ pariwo síta wí pé kò sí nnkan tó ṣe àwọn irẹsi táwọn pín káàkiri láti fi ṣe iranlọwọ fáwọn ipinlẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lásìkò konilegbele yìí.
Ìjọba àpapọ̀ sọ pé gbogbo àwọn irẹsi náà lo wá nibamu láti jẹ, tí kò sì ní ìpalára tí yoo ṣe fún agọ ara àwọn aráàlú tó bá jẹ́ ẹ.
Minisita f'ọrọ ìgbé-ayé ọmọniyan àti ìṣẹ̀lẹ̀ àjálù, Hajiya Sadiya Farouq lo sọ̀rọ̀ náà lásìkò tó ń b'awọn oniroyin sọ̀rọ̀ n'ilu Abuja.
Ó ní kí í ṣe pé àwọn déédéé gbé àwọn irẹsi náà síta fún jíjẹ, bí kò ṣe pé àjọ tó ń ṣabojuto lílo òògùn àti oúnjẹ jíjẹ, ìyẹn NAFDAC tí yẹ àwọn irẹsi náà wò dáradára, wọn si ri í pé kò sí nnkan tó ṣe wọn.
Ontẹ tí àjọ NAFDAC fi lu àwọn oúnjẹ náà lo jẹ́ káwọn gbé e síta láti pín un fún ipinlẹ káàkiri.
Bákan náà lo tún sọ pé lóòótọ́ ni pé bí irẹsi bá ti pẹ lahamọ, ó ṣeé ṣe kó pawọda, ṣùgbọ́n ìyẹn kò sọ pé kò má ṣeé jẹ́.
Laipẹ yìí ni ìjọba ipinlẹ Ọ̀yọ́ àti Ondo pariwo síta wí pé gbogbo irẹsi t'ijọba fi ranṣẹ sì wọn lo tí bajẹ pátápátá, kò sì ṣeé jẹ́, èyí lo mú kí wọn sọ pé àwọn kò lè gbà á, nítorí pé kò síbi táwọn yóò dà wọn sì.
No comments:
Post a Comment