Ẹ JẸ KÁ TẸLE ÌLÀNÀ JÉSÙ OLÚWA - DINO MELAYE PÀRỌWÀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, April 11, 2020

Ẹ JẸ KÁ TẸLE ÌLÀNÀ JÉSÙ OLÚWA - DINO MELAYE PÀRỌWÀ


Ọkàn lára àwọn gbajugbaja sẹnetọ lorilẹ-ede Nàìjíríà, Sẹnetọ Dino Melaye tí pàrọwà sí gbogbo ọmọ orilẹ-èdè yìí, pàápàá àwọn ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ wí pé kí wọn tẹle àwọn ìlànà tí Jésù Olúwa là kalẹ.

Sẹnetọ Melaye lo sọ̀rọ̀ yìí nínú ọ̀rọ̀ rẹ tó fi ń kí àwọn èèyàn fún tí ayẹyẹ ọjọ́ àjíǹde Jésù Kristi Olúwa, èyí tí a bọ sínú rẹ yìí, bẹ́ẹ̀ lo tún ní kí wọn na ọwọ ìfẹ́ síra wọn, pàápàá gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Jésù là kalẹ. 

Nínú atẹjade tí gbajumọ Sẹnetọ tẹ́lẹ̀ fún ẹkùn Kogi West nipinlẹ Kogi náà lo tí ni kò sí asiko tó dára táwọn èèyàn lè fi ìfẹ́ ńlá hàn síra wọn bí kò ṣe irú asiko ti àrùn aṣekupani tí koronafairọs dá gbogbo agbaye láàmú yìí, àti pé ọna láti dá àlàáfíà padà silu nìyẹn.

Bákan náà lo tún gbé oriyin fáwọn ọmọ Nàìjíríà fún ìfaradà àti suuru tí wọn ní láti koju àìsàn aṣekupani COVID-19 náà àti bí wọn ṣe jókòó sílè, tó sì ni fún ìgbà díẹ̀ ni, ati pe ohun tó dára ní bí wọn ṣe fọwọsowọpọ. 

Ó wà rawọ ẹ̀bẹ̀ sijọba wí pé kí wọn túbọ̀ gbìyànjú láti ṣe iranlọwọ nnkan ìdẹ̀rùn fáwọn aráàlú lásìkò konilegbele táwọn èèyàn tẹle òfin ìjọba.

"Gẹ́gẹ́ bí ọmọ Nàìjíríà àti Kristẹni, a ní láti tẹle àwọn ìlànà àti ipasẹ Jésù Kristi Olúwa wa. Àjíǹde ọdún tún fún wa láǹfààní láti rántí àwọn ipasẹ yìí. 

"Lásìkò tí irú nnkan báyìí ń ṣẹlẹ̀ káàkiri orilẹ-èdè àti agbaye, kò sì asiko tó yẹ ká tún hùwà bí Jésù Kristi bí kò ṣe irú asiko báyìí. Èyí yóò dá ìwòsàn àti àlàáfíà padà sí agbaye."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI