DÁHÙN ÌBÉÈRÈ YÌÍ KÍ Ó SÌ JẸ Ẹ̀BÙN - ÌRÒYÌN AWÍKONKO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, April 30, 2020

DÁHÙN ÌBÉÈRÈ YÌÍ KÍ Ó SÌ JẸ Ẹ̀BÙN - ÌRÒYÌN AWÍKONKO


Fún ìgbádùn ẹyin olólùfẹ́ wa, a mú ikiini wá fún un yín lásìkò konilegbele tó ń lọ káàkiri àgbáyé láti dẹkùn itankalẹ aarun aṣekupani Covid-19. 

A ti gbìyànjú láti fún ẹyin olólùfẹ́ wa ni ẹ̀bùn bí agbára wá ṣe ká, fún èèyàn mẹ́wàá àkọ́kọ́ tó bá gba ìdáhùn sí ìbéèrè yìí. 

Ìbéèrè náà rè é:

1. Èèwọ̀ ni kí ojúlówó Ọba aládé ṣiju wo inú adé, àmọ́ Ọba kan ṣoṣo nbẹ tó le ṣiju wo inú adé rẹ.
Kí ni orúkọ oyè Ọba na àti pé ìlú wo ni Ọba náà wà?

2. Gbogbo àwọn tó gba ìyá adé (ojúlówó Adé) ni Ilé Ifẹ̀ gba ẹyọ kọ̀kan, àmọ́ ọba kan nbẹ to ṣe pé Ìyá Adé méjì ló ní í.
Kí ni orúkọ Ọba na àti ìlú tó jẹ́ ọba sì?

Ẹ fi idahun yín ranṣẹ gẹ́gẹ́ bí atẹjiṣẹ sì 07012342712

Ọna láti fi ìdáhùn ranṣẹ 
Orúkọ 
Adugbo àti Ilu
Ìpínlẹ̀ 
Ìdáhùn

Àpẹẹrẹ 
Oruko: Ajadi Ogunbọna
Àdúgbò àti Ìlú: Oke-Paadi, Ibadan
Ìpínlẹ̀: Ọ̀yọ́ 
Ìdáhùn: 1. Oloburo, Ibadan
Ìdáhùn: 2. Olokinu, Ibadan








No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI