AYÉ MÀ LE O! ÀṢÍRÍ ÀWỌN TÓ Ń FI AMỌTẸKUN LU JÌBÌTÌ TU L'ỌTA, ỌWỌ ẸṢỌ ÀÀBÒ SO-SAFE LO TẸ WỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, April 21, 2020

AYÉ MÀ LE O! ÀṢÍRÍ ÀWỌN TÓ Ń FI AMỌTẸKUN LU JÌBÌTÌ TU L'ỌTA, ỌWỌ ẸṢỌ ÀÀBÒ SO-SAFE LO TẸ WỌN


Wọn ní ọjọ́ gbogbo ni ti olè, ọjọ́ kan ṣoṣo náà ni ti olohun, tó sì lọ nibamu pẹlu bí àṣírí àwọn mẹtala kan tí wọn ń fi orúkọ ẹṣọ ààbò ilẹ̀ Yorùbá, ìyẹn AMỌTẸKUN lu àwọn aráàlú ni jìbìtì. 

Nǹkan bí aago mẹ́rin kọjá ìṣẹ́jú mẹ́rìndínlógún {4:16pm} ọjọ Aje, Mọnde àná la gbọ pé àṣírí àwọn ayédèrú òṣìṣẹ́ Amọtẹkun yìí tú sáwọn ẹṣọ ààbò ipinlẹ Ogun, ìyẹn So-Safe Corps.


Agbegbe Lafẹnwa to wá ní Itele-Ọta, ìjọba ìbílẹ̀ Ado-Odo Ọta lọ́wọ́ palaba wọn tí segi, lásìkò tí wọn ń fipá gba owó lọ́wọ́ àwọn aráàlú pẹ̀lú ẹtanjẹ láti dáàbò bo wọn. 

Ọgbẹni Mọruf Yusuf to jẹ alukoro fún ẹṣọ ààbò So-Safe tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ f'AWIKONKO sọ pé asiko táwọn òṣìṣẹ́ wọn ń lọ káàkiri láti rí í pé àwọn aráàlú mú àṣẹ àti òfin ìjọba nípa konilegbele ṣẹ laṣiri àwọn èèyàn náà tú. 


Yusuf sọ pé ṣe ló jẹ́ ìyàlẹ́nu wí pé àwọn èèyàn náà gbé mọto meji ati ọkada mẹta láti máa fi ṣíṣẹ káàkiri, tí wọn sì ń sọ fáwọn èèyàn pé àjọ DAWN, ìyẹn Development Agenda for Western Nigeria lo fáwọn láṣẹ láti máa ṣíṣẹ káàkiri. 

Ní kété táwọn òṣìṣẹ́ SO-SAFE tí rí í pé ayédèrú pọmbele làwọn èèyàn náà ni wọn ti ko wọn lọ teṣan ọlọpaa Itele láti túbọ̀ ṣe ìwádìí wọn. 


Gbogbo akitiyan láti bá Ọgbẹni Abimbọla Oyeyẹmi tó jẹ́ agbẹnusọ fáwọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun sọ̀rọ̀ kò lè fìdí ẹ múlẹ̀ lo ja si pàbó lásìkò tá a kọ ìròyìn yìí tán. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI