ÀWỌN ỌMỌ ẸGBẸ́ ÒKÙNKÙN MI-IN TUN WỌ GAU N'IFỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, April 11, 2020

ÀWỌN ỌMỌ ẸGBẸ́ ÒKÙNKÙN MI-IN TUN WỌ GAU N'IFỌ


Àwọn tí ẹ ń wo yìí lọ́wọ́ ọlọpaa ipinlẹ Ogun tún ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ. Lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tí wọn dá wàhálà silẹ, tí wọn sì tún ń lo àǹfààní ẹ láti ja àwọn èèyàn lólè ni wọ̀nyí. 


Ohun tí a gbọ ni pé àwọn tí kò dín ni marundinlọgbọn tí wọn ń dá agbegbe Ifọ, Sango, Àgbàdo àti agbegbe wọn rú lọ́wọ́ palaba wọn tí segi laarin ọjọ́ mẹta.


Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, DSP Abimbọla Oyeyẹmi fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ lónìí, tó sì làwọn kò ní fojú kan oorun dìgbà tí ọwọ yóò fi tẹ gbogbo wọn, tí àlàáfíà yóò sì padà silu. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI