Laipẹ yìí ni fọ́nrán kan gbà orí ayélujára níbi táwọn ọlọpaa méjì kan tí ń lu iyaale ilé kan lágbègbè Odo-Ori, Iwo, nipinlẹ Ọṣun.
Ẹ̀sùn tá a gbọ pé àwọn ọlọpaa náà fi kan obìnrin yìí ni pé ó lugbadi òfin konilegbele, tó sì jẹ pe wọn kò iya ajẹkudorogbo fún un.
Bi fọ́nrán yìí ṣe káàkiri tó, ní wọn tí pé àkíyèsí ileeṣẹ ọlọpaa sì í, èyí ló mú kí ọga ọlọpaa orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pàṣẹ wí pé kí wọn ṣèwádìí àwọn ọlọpaa náà, kí wọn sì fi wọn jofin.
Nígbà tọwọ palaba wọn máa segi, ní wọn rí í pé àwọn ọlọpaa tí wọn pé orúkọ wọn ní Ikuẹsan Taiwo àti Abass Ibrahim ni wọn ṣiṣẹ náà.
Lójú ẹsẹ ni wọn ti gba aṣọ lọrun wọn, wí pé wọn kò yẹ lẹni tó ń ṣiṣẹ agbofinro.
No comments:
Post a Comment