ÀWỌN ADIGUNJALE YA WỌ ILE GBAJUMỌ OLORIN, WỌN GÙN-ÚN YANNA-YANNA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, April 11, 2020

ÀWỌN ADIGUNJALE YA WỌ ILE GBAJUMỌ OLORIN, WỌN GÙN-ÚN YANNA-YANNA


Orin ọpẹ làwọn olólùfẹ́ gbajumọ olorin takasufe tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dìde bọ, ẹni tí wọn pé orúkọ rẹ ni Stain Lace lórí báwọn adigunjale ṣe yà wọ ilé rẹ, tí wọn sì gún un ṣìbáṣìbo. 


Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orí lo kò Stain Lace yọ lọ́wọ́ àwọn adigunjale náà, ṣùgbọ́n síbẹ̀, kò lè tètè gbàgbé ìṣẹ̀lẹ̀ náà títí ayé.


Ọmọ bíbí ìlú Akwa-Ibom náà là gbọ pé òru àná mọjumọ òní làwọn adigunjale náà lọ ká a mọle, tí wọn sì gba àwọn dúkìá mélòó kan lọ́wọ́ ẹ. 


Àwọn aráàdúgbò la gbọ́ pé wọn sáré gbé e lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú lẹ́yìn táwọn adigunjale náà tí na pápá bora.


Fúnra rẹ lo gbé ìṣẹ̀lẹ̀ náà sáwọn èèyàn létí lórí ìkànnì ayélujára tí Fesibuuku laipẹ yìí, tí wọn sì ń bá a dúpẹ́.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI