Ko sẹni to ri bi Samuẹl Ṣobayọ to pe ara rẹ ni Wolii ọsan gangan ṣe n sọrọ
nilu Abẹokuta laipẹ
yii, ti ko ni i ṣiye meji pe iranṣẹ eṣu pombele ni, ṣugbọn to jẹ pe orukọ
Ọlọrun lo fi n lu
awọn
eeyan ni jibiti.
Ohun to n ṣe ọpọ eeyan ni kayeefi lori ọrọ Samuel
ni ẹbọ ti wọn lo maa n ni k’awọn to ba lo ṣiṣẹ lodo ẹ gbe laaarin oru, ti yoo
si tun ko ibasun f’awọn obinrin, paapaa awọn iyaale ile, ko da, ti wọn lo o ti
wa lẹnu
iwa naa tipẹ.
Iyaale ile kan ta a forukọ bo laṣiri la gbọ pe
Samuel fipa ko ibasun fun karakara ninu ile aabo ṣọọṣi ẹ to wa lagbegbe
Oke-Akingbala, Ọbantoko,
nilu Abẹokuta.
AWIKONKO gbọ pe iṣẹ itusilẹ ni Samuel l’oun fẹ ẹ ṣe
fun obinrin naa, ko to o di pe o sọ fun un wi pe afi k’oun ba a laṣepọ to ba fẹ ki iṣẹ
itusilẹ naa tete dahun.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn
ni ọdun
mẹfa
sẹyin
re e
ti iyaale ile naa ṣa
dede bẹrẹ
si i mu ọti
karakara, ti wọn si lo n ṣe ọpọ eeyan ni kayeefi. Ọpọ awọn ile itọju la gbọ pe
iyaale ile naa ti lọ
lati jawọ kuro ninu ọti
mimu, ṣugbọn to jẹ
pe pabo lo n ja si, to si maa n da ija silẹ laarin oun ati ọkọ
rẹ.
Oṣu kan sẹyin la gbọ pe
obinrin naa tun mu ọti
yii lamu-paara, ti wọn si lo o gbagbe ara rẹ sinu oko kan to wa ladugbo wọn. Ibẹ
si ni wọn sọ pe ọkunrin
kan ti wọn pe ni Baba Iyabọ ti ri i, to fi l’oun yoo mu lọ si ṣọọṣi kan to
ti le ri igbala si iṣoro
aye ẹ.
Ọjọ keji ni wọn ni
Baba Iyabọ mu obinrin naa de ṣọọṣi Samuel, to si l’oun yoo ṣiṣẹ
itusilẹ ọlọjọ
meje fun un, ati pe aarin oru ni pupọ rẹ yoo jẹ, nitori naa, o
ni afi ko wa a ṣe igbele ọlọjọ meje ni ṣọọṣi
oun.
Wọn ni obinrin naa
sọ pe oun ko le ṣe igbele, tori pe ọkọ oun ko ni i gba
oun laaye. Idi re e
ti wọn lo o fi ṣiṣẹ kan fun un, ṣugbọn ti iṣẹ naa pada bajẹ nitori nnkan oṣu rẹ to ri. Eyi
gan an lo mu ki Samuel sọ pe afi ko wa ṣe iṣẹ itusilẹ naa laarin aago mọkanla si aago
kan oru, nitori iwẹ
ati ẹbọ
ti yoo gbe.
Ọjọ akọkọ ti iṣẹ naa bẹrẹ ni wọn sọ pe
Samuel sọ fun obinrin naa wi pe afi k’oun ba a laṣepọ ko to o le gbe ẹbọ lọ s’ikorita, eyi
ti yoo jẹ
k’iṣẹ naa le tete dahun, ti wọn si ni ṣe lobinrin naa yari pe ko le ṣee ṣe, ṣugbọn ti
wọn lo o fọgbọn tan an wọ yara aabo ti wọn
ti n gbadura, to si fipa ko ibasun fun un karakara.
Ọjọ ti iṣẹ naa yoo pari la gbọ pe Samuel tun ko
ibasun fun obinrin yii, ti wọn si ni ṣe lobinrin naa muu mọra pẹlu igbagbọ wi pe oun yoo
ri itusilẹ, ti ko si sọ fun ọkọ rẹ n’ile.
Ṣaaju asiko yii
la gbọ pe awọn kan ladugbo ti wọn n ri obinrin naa ti pe ọkọ
rẹ si akiyesi wi
pe awọn maa n ri iyawo rẹ laaarin oru, ti yoo yọ kẹlẹkẹlẹ lọ si ṣọọṣi, to si
ṣee ṣe ko jẹ pe ale rẹ lo lọ naa ba. Idi re e ti wọn ni ọkọ obinrin naa fi ṣe
iwadii, to si pada jẹ
pe otitọ
ni.
Ọrọ yii la gbọ pe o
da wahala silẹ
laarin obinrin yii ati ọkọ
rẹ, bo tilẹ jẹ pe ọtọ lẹni ti ọkọ
rẹ ro tẹlẹ wi pe o n yan
iyawo oun ni ale, ṣugbọn ti aṣiri pada tu wi
pe Samuel t’awọn eeyan n wo gẹgẹ bi Oluṣọ ni.
Ṣaaju asiko yii
la gbọ pe pasitọ
naa maa n yọ
lọ
sile obinrin yii lati ba a laṣepọ lasiko ti ọkọ
rẹ at’awọn ọmọ ko ba si nile
laarọ
ati alẹ,
ṣugbọn ti i nnkan naa ṣe, to si jẹ pe ọjọ kan ni aṣiri fẹ ẹ tu, to
si ri anfaani lati na papa bora.
Ọkọ obinrin naa
n’igba to n sọrọ
sọ pe oun ko mọ pe inu ewu loun
wa lati bi oṣu
mẹta
sẹyin
ti iyawo oun ti n yan ale, to si lẹnikan lo tu aṣiri naa f’oun ko
to o di pe oun pada ri okodoro ọrọ.
O ni nnkan ti ko jẹ koun mọ ni pe yara ọtọọtọ
lawọn jọ
n sun si, ati pe oun ko ronu nnkan bẹẹ si i ri. O lọjọ ti aṣiri yii maa tu,
nnkan bi aago mejila ku iṣẹju mẹẹdogun loun taji,
toun si lọ
wo iyawo oun ninu yara, ṣugbọn toun ko ba, eyi lo mu koun lo o jokoo
de niwaju ita, toun si ri i lasiko to sapamọ sinu ọgẹdẹ nigba ti aṣiri ẹ fẹẹ tu sọwọ pasitọ kan to n gbe
iwaju ile wọn.
Baale ile naa sọ pe kaka ki iyawo oun maa bebe, ṣe
lo fesun kan oun wi pe oun ko toju oun, ati pe oun n lo s’ọdọ awọn to mo itọju
obinrin ṣe ni, to si ṣee
ṣe koun keru jade ki ọdun yii to o pari.
Ọkunrin naa tun sọ pe ọrọ naa to su oun lo je
koun loo fejo sun Baba Imole, tawọn si lo beere nnkan to sele lodo Oluṣọ
Samuel, o ni Oluṣọ naa sọ pe Baba Iyabọ lo mu iyawo oun wa si ṣọọṣi, ati pe ṣọọṣi
naa ni wọn ti n ko ibasun funra wọn.
“Inu ile ni mo wa ti lose to koja lo lohun ti Oluṣọ yii tun ti wa a ba iyawo mi ni nnkan bi aago mewa koja iseju die, ti wọn jọ n sọrọ. Ko pe lo wa ki mi, ti mo si sọrọ buruku si i. ibe la ti bere ija, to fi ki ada mole, to si bere si i sa iyawo mi wi pe o tu aṣiri fun mi, ti ko si ri bee.”
Obinrin naa ninu ọrọ rẹ sọ pe Baba Iyabọ lo ran
oun lọwọ de ọdọ Oluṣọ
Samuel to si ṣiṣẹ itusilẹ f’oun, ati pe igbele ọjọ meje loun ṣe, ṣugbọn toun
yari pe oun ko le ṣe igbele.
O niṣe ọna ti Samuel kọkọ ṣe foun bajẹ nitori pe
asiko naa loun ri nnkan oṣu oun, ati pe afi koun maa wa loru nitori awọn akanse
iṣẹ to ro mo oru. L’ọjọ akọkọ, ṣe ni Oluṣọ sọ pe ki n to gbe ipese (ẹbọ) lo si
ikorita mẹta, afi ka jọ ni aṣepọ, mo si sọ pe mi o le ṣe ẹ.
“Igba ti a de lati ibi ti a gbe ipese lo laago kan oru ni mo wo yara aabo, to si sare wọle tẹle mi, o tilẹkun lẹyin, o si fipa ba mi laṣepọ. Lẹyin ọjọ karun-un ki iṣẹ naa to o pari, Oluṣọ tun ba mi laṣepọ ninu ile aabo, ti mo si sọ fun Baba Iyabọ, ṣugbọn to ni ki n ṣe suuru niwọn igba to jẹ pe itusilẹ ni mo n wa, nitori naa ki n gba kamu.
“Ẹlẹẹkẹta lo sọ pe ikorita ni maa ti wẹ lo jẹ ki n tun ranṣẹ pe Baba Iyabọ lati ran mi lọwọ, nitori pe mi o le gba ko ba mi laṣepọ lẹẹkẹta. Alaalẹ ni Oluṣọ maa n wa sile wa, ti mo si ti kilọ fun laimọye igba.
“Eyi to wa gbẹyin yii lo di wahala. Ibẹ lo ti ro pe mo ti sọrọ fun ọkọ mi, ti mi o si sọ nnkankan. O sọ pe Baba Iyabọ lo n gbe mi wa si ṣọọṣi lati ba mi laṣepọ wi pe ki i ṣe oun, ti ọrọ naa si di wahala nla gidi. Ko pe lawọn eeyan pe mi wi pe mi o gbọdọ de ṣọọṣi naa mọ tori pe Oluṣọ ti leri wi pe oun yoo pa mi danu.
“Ounjẹ ni mo fẹ lo ra ti mo fi gba ẹgbẹ ṣọọṣi naa kọja, bi Oluṣọ ṣe ri mi lo sare wa ba mi, to si fun mi n’igbati mẹjọ, ṣe lo tun sare lọ ọ mu ada pana, to si bẹrẹ si i fi lu mi, ti gbogbo ara mi bajẹ, o tun gba ẹgbẹrun kan ati igba (1200) naira lọwọ mi. Ẹ gba mi lọwọ ẹ o.”
N’igba t’oun naa n tako ẹsun ti wọn fi kan an,
Samuel sọ pe “Ọti
ni wọn lo n mu, ti wọn fi muu wa s’ọdọ mi, mo si ba a ṣe ipese to gbe lọ ọ si ikorita. Afi
ki Ọlọrun ṣaanu
mi lori ọrọ yii. Inu ile aabo la ti jọ laṣepọ, funra rẹ lo si gba fun mi, ki i ṣe
pe mo fipa muu rara.
“Ẹẹkan ṣoṣo pere ni mo ba a laṣepọ, funra rẹ lo wa a ba mi ninu yara lẹyin to gbe ipese tan wi pe ki n ba oun laṣepọ, ti mo si gba fun un. Mi o ṣa lada, pẹtẹpẹtẹ ada ni mo fi luu, mo si ko ẹṣẹ bo o n’igba to wa pariwo le mi lori. Igi ina ti mo yọ, mo kan fi halẹ mọ-ọn lasan ni, mi o fi luu.
“Ko si ninu bibeli wi pe ka ba iyawo oniyawo laṣepọ, ṣugbọn mo mọ pe Ọlọrun yoo dari ji mi. Mo fẹ k’awọn eeyan foju aanu wo mi. Iyawo mi si ti kilọ fun mi lọpọ igba, ṣugbọn ko sẹni ti eṣu ko le ya lo, eṣu lo ya mi lo.”
No comments:
Post a Comment