AKEEM TÓ Ń ṢE BÍ I ALAAGANNA L'ABẸOKUTA WỌ GAU, ỌTÍ ẸLẸRINDODO TÓ Ń MÚ LỌ́WỌ́ LO ṢÁKOBA FÚN UN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, April 20, 2020

AKEEM TÓ Ń ṢE BÍ I ALAAGANNA L'ABẸOKUTA WỌ GAU, ỌTÍ ẸLẸRINDODO TÓ Ń MÚ LỌ́WỌ́ LO ṢÁKOBA FÚN UN


'Atijẹ atimu lo sún mi dé bẹ, ẹ ṣàánú mi, kí i ṣe ẹjọ́ mi. Mí ó ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ' tí lọrọ ẹbẹ tó ń tẹnu gendekunrin kan, Akeem Akanni jáde nígbà tọwọ Fijilante, VGN tẹ ẹ.

Abẹ biriiji Kutọ lọ́wọ́ palaba Akeem tí segi lọsan gangan. 

Ohun tá a gbọ ni pé ọtí ẹlẹrindodo, ìyẹn Coke ti wọn lòun àti ọrẹ rẹ tòun ti na pápá bora lo ṣàkóbá fún un.


Loju ẹsẹ ti àṣírí rẹ tí tú lo tí ń rababa bẹbẹ fún ìdáríjì. 

Ọga àgbà ẹgbẹ́ Fijilante nipinlẹ Ogun, Kọmanda Ọlanrewaju Adedoyin nígbà tó ń gbé ìròyìn náà sì AWIKONKO létí lo tí sọ pé àwọn tí fà á lé àwọn ọlọpaa lọ́wọ́ láti túbọ̀ ṣe ìwádìí ẹ síwájú sí í.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI