Ìjọba ipinlẹ Kwara tí ṣàpèjúwe ikú olórí àwọn òṣìṣẹ́ Ààrẹ Buhari, Abba Kyari gẹ́gẹ́ bí àdánù ńlá fún orilẹ-èdè Nàìjíríà, pàápàá àwọn aráàlú.
Gomina ipinlẹ náà, AbdulRahman AbdulRazaq lo sọ̀rọ̀ yìí nínú atẹjade tó fi síta lópin ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí, ọjọ́ Satide àná láti kẹ́dùn ikú Abba Kyari.
Nínú atẹjade náà tí agbẹnusọ Gomina AbdulRazaq, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye fi síta lo tí ni iru èèyàn bí Olóògbé Abba Kyari ṣọnwọn láwùjọ nípa àwọn ipa rere tó ti ko lórí idagbasoke àti ìlọsíwájú Nàìjíríà.
O ni ẹkọ ńlá lo yẹ kí ikú Kyari jẹ́ fún gbogbo ọmọ Nàìjíríà láti fòwọsowọpọ pẹ̀lú ìṣọ̀kan, ká sì ṣiṣẹ papọ fún idagbasoke ìlú.
No comments:
Post a Comment