Gomina ipinlẹ Kwara, Malaamu AbdulRahman AbdulRazaq tí ṣàpèjúwe Alaaji Ṣhehu Usman Mustapha gẹ́gẹ́ bí adarí rere tó ṣeé f'ọkan tán láwùjọ, àti pé olóòótọ́ t'awọn èèyàn kò gbọ́dọ̀ kò ọ̀rọ̀ rẹ dànù ni.
Ana, tí i ṣe Wẹside ni Gomina AbdulRazaq sọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó ń kí Alaaji Shehu Mustapha tó jẹ́ Wali t'ilu Ilọrin fún ayẹyẹ ọjọ́ ìbí àádọ́rùn-ún.
Nínú atẹjade tí akọ̀wé fún gómìnà, Rafiu Ajakaye fi síta lo tún ti lo tí sọ pé àpẹẹrẹ rere ní igbe ayé Alaaji Mustapha jẹ fún ọpọ èèyàn, pàápàá àwọn ọmọ ẹlẹ́sìn Isilaamu.
"Gomina bá ọkàn lára àwọn àgbà ìlú yọ fún ayẹyẹ ọjọ́ ìbí àádọ́rùn-ún ọdún láyé. Gomina darapọ mọ gbogbo ẹbí, ọrẹ àti ojulumọ bàbà wá dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọhun Allah fún ẹmi gígùn tó kún fún sinsin Ọlọhun ati èèyàn."
No comments:
Post a Comment