Aarun to ju Coronavirus ṣi n bọ laipẹ - Wolii
Gbajugbaja Wolii ti Ọlọrun n lo lati sọ asọtẹlẹ, t'awọn asọtẹlẹ rẹ si n ṣe titi di asiko yii, Wolii Sunday 'Dare Iyunade ti sọ pe Ọlọrun funra rẹ lo ran aarun to n ja kaakiri agbaye bayii, iyẹn Coronavirus sita.
Wolii Iyunade to jẹ alakoso ati oludasilẹ ṣọọṣi Pentecostal Sanctuary Bible Church to wa n'ilu Ijẹbu-Ode lo sọrọ naa laipẹ yii l'asiko to n b'awọn oniroyin kan sọrọ.
O ni aarun Coronavirus ko ṣẹyin imọ Ọlọrun, ati pe Ọlọrun funra rẹ lo ran aarun naa sita lati fi da ipejọpọ ati imọ awọn alagbara agbaye kan ti wọn fẹẹ da ogun nla silẹ ru.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Ọlọrun lo gbe aarun yii kalẹ lati fi da imọ awọn alagbara agbaye kan ru, nitori pe ijamba nla ni wọn n gbero lati ṣe fun agbaye, eyi lo jẹ ki Ọlọrun paṣẹ aarun naa saarin wọn, to si ti n tan kaakiri agbaye bayii.
“Bi e ba ranti daadaa, nigba Ọba Dafidi ninu bibeli, Ọlọrun ran aisan kan n’igba ti wọn n gbero buruku, ṣugbọn nigba ti wọn ri i pe
gbogbo ilu ti fẹ ẹ parun tan, awọn eeyan dide adura, Ọlọrun si mu aisan naa
kuro, bẹẹ gẹlẹ lọrọ Coronavirus ri, adura lo le ṣẹgun ẹ.
"Ko tan sibẹ, a fi ki ajọ eleto ilera agbaye, iyẹn World Health Organization {WHO} tun lọ maa
gbaradi fun aarun mi-in to n bọ lọna, eyi to tun ju Coronavirus lọ. Mi o ti i
le sọ igba ati akoko ti aarun naa yoo de, ṣugbọn o n bọ lọna."
No comments:
Post a Comment