Alaga ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) lorilẹ-ede Nàìjíríà lapapọ, Kọmureedi Adams Ọṣiọmọlẹ tí rawọ ẹ̀bẹ̀ sì gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà, pàápàá àwọn àgbààgbà wí pé kí wọn forijin òun, nítorí pé òun ti rí àwọn òṣìṣẹ́ t'oun ṣe, tòun sì ṣetan láti ṣe àtúnṣe.
Ana tí i ṣe Tuside ni Ọṣiọmọlẹ sọ̀rọ̀ náà n'ilu Abuja, tó sì lòun tí ṣetan láti fọwọsowọpọ pẹ̀lú gbogbo alẹnulọrọ nínú ẹgbẹ́ náà, kí ìlọsíwájú àti ìfẹ́ lè túbọ̀ jọba.
Bẹ ó bá gbàgbé, ọjọ́ kẹrin oṣù yìí ni ile ẹjọ́ gíga n'ilu Abuja jawe lọọ gbele ẹ fún Ọṣiọmọlẹ, tí ọrọ náà sì dá awuyewuye silẹ láti bí ọsẹ mẹ́ta sẹ́yìn.
Ọṣiọmọlẹ lòun mọ pe bí wọn ṣe tọ oníkálukú yàtọ̀, tonikalu sì niilana tó fi ń gbé ilé ayé. Ó ní òun ojú òun ti là dáadáa sáwọn ibi àṣìṣe òun tó dá wàhálà ẹgbẹ́ silẹ, àti pé òun yóò fọwọsowọpọ́ pẹ̀lú gbogbo àwọn tó ní í ṣe nínú ẹgbẹ́.
No comments:
Post a Comment