Bó bá ṣe pé Sẹnetọ tẹ́lẹ̀ n'ipinlẹ Kogi, ìyẹn Dino Melaye mọ pe nnkan yóò padà yiwọ mọ òun lọ́wọ́ ni, bóyá kí bá ti wá nnkan mi-in ṣe, nítorí pé ọjọ́ Aiku tí í ṣe Sannde àná kii ṣe ọjọ́ tó dùn fún ọkùnrin náà rárá nítorí b'awọn olólùfẹ́ rẹ ṣe yẹyẹ rẹ níta gbangba.
F'awọn to bá mọ Dino Melaye dáadáa, wọn a mọ pe ọkùnrin náà fẹran afẹfẹ-yẹyẹ dáadáa, tó sì tún fẹ́ràn afẹ-aye.
Sẹnetọ Dino Melaye gbajumọ dáadáa lorilẹ-ede yìí, ko da, táwọn kan tún fún un loriṣiriṣi órúkọ bí í 'Adẹrinpoṣonu Sẹnetọ', 'Sẹnetọ Onijo' àti bẹẹ bẹẹ lọ.
Aṣọ àwọn tó rí igboro dáadáa kan ni Sẹnetọ Melaye wọ lánàá, tó sì tún wọ ṣòkòtò tí wọn ń pè ní 'Ripped Jeans', to sì fi yà fọto. Aṣọ náà lo jẹ́ pé àwọn gendekunrin, ìyẹn àwọn ọdọ lo ń wọ ọ gidi lásìkò yìí.
Bí Melaye ṣe gbé fọto aṣọ náà sórí ìkànnì ayélujára l'awọn èèyàn, pàápàá àwọn olólùfẹ́ rẹ tí bẹ̀rẹ̀ si í sọ̀rọ̀ burúkú sì í wí pé kò nironu kankan rárá.
B'awọn kan ṣe ń pè ní 'agbaya', bẹ́ẹ̀ làwọn kan ń sọ pé 'alailojuti' ni. Wọn ní aṣọ tó yẹ kí àwọn ọmọ rẹ máa wọ lòun kò sọrun, tó tún fi ń ṣakọ.
Ọrọ yìí là gbọ́ pé ó dùn Sẹnetọ Melaye, tí kò sì lè sọ̀rọ̀ nígbà táwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ si í bù ẹnu atẹ luu, tó sì ṣe bí ẹni tí kò rí í.
No comments:
Post a Comment