O PARI O! AWỌN DOKITA DA IṢẸ SILẸ NITORI CORONAVIRUS - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, March 17, 2020

O PARI O! AWỌN DOKITA DA IṢẸ SILẸ NITORI CORONAVIRUS

'Ara ko r'okun, ara ko ro adiẹ' l'awọn dokita n'ilu Abuja ti pe ọrọ naa bayii, pẹlu bi wọn ṣe sọ pe bi ijọba apapọ ko ba tete wa nnkan ṣe sọrọ aarun Coronavirus to n tan kaakiri agbaye lasiko yii.

Aarẹ ẹgbẹ awọn dokita, Roland Aigbovo ninu atẹjade to bu ọwọ lu lo ti f'idi ẹ mulẹ wi pe awọn dokita ko ni i pada sẹnu iṣẹ ayafi bijọba ba le wa nnkan ṣe si iṣẹlẹ yii.

Onii ti i ṣe Tuside l'awọn dokita naa bẹrẹ idaṣẹsilẹ naa lori bi wọn tun ṣe ri aarun naa lara ẹlomi-in.

Roland sọ pe ko si eto itọju to pe ye l'awọn ọsibitu kaakiri, ti ko si tun si eto aabọ f'awọn to ni aarun naa, at'awọn alaisan.

O tun jẹ ko di mimọ pe pataki idi t'awọn fi n lọ si idaṣẹsilẹ alailọjọ ni ti owo oṣu meji ti wọn ko san f'awọn, to si lo o digba t'awọn ba gba owo ọya wọn k'awọn to o pada sẹnu iṣẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI