Ó MÀ ṢE O: WỌ́N DÁ ẸJỌ́ IKÚ FÚN KAREEM TÓ JÍ FÓÒNÙ L'ÉKÌTÌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, March 2, 2020

Ó MÀ ṢE O: WỌ́N DÁ ẸJỌ́ IKÚ FÚN KAREEM TÓ JÍ FÓÒNÙ L'ÉKÌTÌ


Lọ́jọ́ Fraide ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí n'ile-ẹjọ gíga fò f'ikalẹ silu Ado-Ekiti pàṣẹ wí pé kí wọn lọọ yẹ igi fún ọdọmọkunrin kan tí wọn pé orúkọ rẹ ni Isa Abdulkareem lórí ẹ̀sùn méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọn fi kan an, èyí tó nii ṣe pẹ̀lú olè jija. 

Ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù Kejìlá ọdún 2016 là gbọ̀ pé Kareem lọọ ja ẹnikan tí wọn pé orúkọ ẹ ní Taiwo Ọlọmọla pẹ̀lú ìbọn àti ada, tó sì gba fóònù pelu owó ẹgbẹ̀rún lọ́nà aadọfa {110,000} naira lágbègbè Ureje, Ado-Ekiti. 

Ìyẹn nìkan kọ́, wọn ní Kareem tún lọọ ja ẹni tí wọn pé orúkọ ẹ ní Adeja Ọlalekan lólè fóònù Infinix Note 2 pẹ̀lú owó tí jọ dín ni ẹgbẹ̀rún mẹ́rinlelaadọrin {74,000} naira, èyí tí wọn lo ó lòdì sí òfin ọ̀daràn t'ọdun 2012.

N'igba to ń gbé idajọ náà kalẹ, Onidajọ Mosunmọla Abọdunde sọ pé gbogbo àwọn ẹri tó wà níwájú òun kò tako ìwádìí, tó sì fìdí mulẹ pé ọ̀daràn paraku ni Kareem. 

Fún ìdí èyí, ó ní ìdájọ́ ikú lo tọ sii, tó sì pàṣẹ pé kí wọn lọọ yẹ igi fún un títí ẹmi yóò fi jabọ lára rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI